Jump to content

Fredrick Kúmókụn Adédeji Haastrup

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ajimoko I
Reign April 1896 – September 1901
Coronation April 1896
Predecessor Owa Alowolodu
Successor Owa Ataiyero
Spouse
Christiana Fagumell (m. 1848)
Issue
  • Princess Adenibi, Prince Adekolupo
  • 10 other children

Àdàkọ:Endplainlist

Full name
Frederick Kumokun Adedeji Haastrup
House Bilaro / Oro Royal Family
Father Owa Oweweniye
Mother Ayaba Owa Obokun
Born (1820-01-01)1 Oṣù Kínní 1820
Ilesa, Kingdom of Ijesaland
Died 1 September 1901(1901-09-01) (ọmọ ọdún 81)
Ilesa, Protectorate of Southern Nigeria

Fredrick Kúmókụn Adédeji Haastrup jé ẹni tí wọ́n bí ní sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún sínú ìdílé ọlọ́la ti Bilaro ti ìlú Iléṣa. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìdílé mérin tí wọ́n ti máa ń yan ẹni tí á máa darí ìlú nígbà náà, lára àwọn ìdílé náà ni (Biládù, Bilágbayọ, Biláro, and Biláyiréré)[1] èyí sì ti wà láti ìgbà ìṣèjọba Owá Ọbọkun Atakumosa, láti bí i ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn (900 years ago). Lẹ́yìn ìṣèjọba rẹ̀, ètò ìṣèjọba kan àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn ìdílé Bilárọ mú orúkọ rẹ̀ mọ́ra, wọ́n sì ń jẹ́ Ajímọkọ Haastrup. Nígbà tí Bilágbayọ mú orúkọ Adesuyi.

Wọ́n lo orúkọ Ajímọkọ fún ìdílé tó bá ń ṣètò ìjọba.

Èrò nípa ìdílé náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lásìkò ọdún 1820s-30s, nígbà tí ó wà ní bí i ọmọ ọdún mẹ́rin sí mẹ́sà-án (4-9 years old), àwọn ará Ilorin mú Kúmókụn nígbà tí wọ́n ran níṣẹ́ , wọ́n sì sọ ọ́ di ẹrú.[2][3] Wọ́n gbe kúrò láti ibìkan lọ sí ibòmìíràn, títí tí wọ́n fi dé ìkoríta tí wọ́n fi fi sí inú ọkọ̀ ẹlẹ́rú, tí wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sọ ó lẹ́sẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹrú mìíràn. Ọkọ̀ ojú omi náà sì ń lọ sí ìbùdó rẹ̀, àmọ́ Kúmókụn ṣàìsá̀n. Ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ni pé adarí ọkọ̀ náà ń jẹ́ Haastrup.[4] Ó sì kúndùn arákùnrin yìí. Ìfẹ́ tó ní si yìí ló mú kí ó tú u sílẹ̀, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní tọ́jú rẹ̀. Bí wọ́n sì ṣe wà lórí ọkọ̀ ojú omi, àwọn ará ìlú Britain fagilé ètò ìkónilẹ́rú, èyí sì mú kí ọkọ̀ yìí sọ ẹ̀tọ́ rẹ̀ nù. Ọkọ̀ yìí kan náà ni àwon ológun ṣígun lé[5] wọ́n sì kó àwọn ẹrú yìí lọ sí ìlú Sierra Leone. Ní Sierra Leone, Kúmókụn di ọmọ Capt. Haastrup, tí ó sì bójútó ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ [4].

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Sir Familusi, M.M. KJW (2004) Royal Ambassador Life of Sir Adedokun Abiodun Haastrup KJW. Ibadan: J.P. Heinmann Educational Books (Nigeria) Plc. p. 8 second paragraph
  2. Sir Familusi, M.M. KJW (2004) Royal Ambassador Life of Sir Adedokun Abiodun Haastrup KJW. Ibadan: J.P. Heinmann Educational Books (Nigeria) Plc. p. 9 second paragraph
  3. Peel, J.D.Y. (1983) Ijeshas and Nigerians. Cambridge: Cambridge University Press African Studies Series 39. p. 92 third paragraph
  4. 4.0 4.1 Sir Familusi, M.M. KJW (2004) Royal Ambassador Life of Sir Adedokun Abiodun Haastrup KJW. Ibadan: J.P. Heinmann Educational Books (Nigeria) Plc. p. 10 second paragraph
  5. "Ajimoko I - NigerianWiki". Nigerianwiki.com. Archived from the original on 13 September 2018. Retrieved 13 September 2018.