Funmi Wakama

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

A bí Funmi Wakama ní ìlú Èkó ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje ọdún 1966 gẹ́gẹ́ bíi Olufunmilayo Yetunde Coker. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣé akọ̀ròyìn rẹ̀ ní ọdún 1985 gẹ́gẹ́ bíi akọ́ṣẹ́ ní Lagos Television, LTV 8, Lagos kí ó tó lọ sí Nigeria Television Authority, Abeokuta ní ọdún 2018.

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe ti ìlú Ogun èyiun Ogun State Polytechnic tí ó ń jẹ́ Moshood Abiola Polytechnic báyìí ni ó ti kẹ́kọ̀ọ́ Mass Communication.[1] Bákan náà, ó ní ìwé ẹ̀rí gíga nínú ìkóròyìnjọ láti the Nigerian Institute of Journalism, NIJ; ẹ̀wẹ̀, ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀/ẹ̀kọ́ Public Administration láti ilé ẹ̀kọ́ gíga ti Abuja, èyiun University of Abuja.

Funmi Wakama yìí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àgbà lábala mídíà fún Gómìnà tẹ́lẹ̀rí ní ìpínlẹ̀ Ogun, Gómìnà Ibikunle Amosun. Ó jẹ́ alábòójútó mídíà ní International Republican Institute (IRI), fún ètò USAID ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[2][3][4]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "NTA's Funmi Wakama: The Golden Fish Soars at 55". oyonews.com.ng. 2021-07-01. Retrieved 2021-12-01. 
  2. "Watching Cyril Stober, Wakama, others inspired my career choice –Broadcaster in wheelchair, Awoyemi". Punch Newspapers. 2021-10-22. Retrieved 2021-12-01. 
  3. "Mrs Funmi Wakama – Radio Nigeria Ibadan Zonal Station". radionigeriaibadan.gov.ng. Retrieved 2021-12-01. 
  4. "Funmi Wakama: The screen diva joins the Golden Club". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. 2016-07-02. Retrieved 2021-12-01.