Jump to content

Gèlè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Gèlè jé irúfé aṣọ tí a máa n gbá mọ́ orí. Kòsí aṣọ tí o leè wuyì-wúni-lórí lára obìnrin Yorùbá láìsì gèlè. Gèlè ti wá di gbajú-gbajà láàrín àwọn obìrin ní gbogbo orílẹ̀-èdè wa Nàìjíríà.[1]

Gèlè jẹ́ ǹkan pàtàkì tí ọmọ-bìnrin kìí fií falẹ̀ lọ́jọ́ ayẹyẹ Ìgbéyàwo wọn. Bákannaáà ni, àwọn alábáṣe kò gbẹ́hìn. A sì tún se àmúlò rẹ̀ níbi ayẹyẹ ìsìnkú tàbi oríṣi ayẹyẹ míràn.

Gèlè tí a ṣe pẹ̀lú aṣọ tí a mọ sí dàmáàsì wuyì púpò lásìkò tirẹ̀( bí ótilẹ̀ jẹ́ wípé àsìkò rẹ̀ ti kọjá). Ó ṣe é gẹ̀ dáadáa sí orísi onà tí a fẹ́ fi da.[2][3] Bí Gèlè bá ṣe ga tó, ni ẹwà a rẹ̀ yíó ṣe pọ̀ to. Olórin Lágbájá kọ orin "Oní Gèlè" nínú àwo-orin "Skentele Skontolo"The higher the gele is, the more beautiful it is. Even Lagbaja sang a song about an “Oni Gele” in a track called “Skentele Skontolo”. Àwọn kan a máa da láṣà pé, bí gèlè bá ṣe tóbi tó ni inú ẹni wée sórí ṣe dùn to, àti pe, Gèlè ò dùn bíi ká mọ́ọ́ wé, ká mọ́ we ò dà bíi kó yẹ ni.

Àrọbá kan sọ wípé, gèlè wíwé a máa sọ ìyàtọ̀ láàrín abilékọ àti omidan. abilékọ a gẹ gèlè sápá ọ̀tun bẹ́ẹ̀ ni omidan a gẹ tirẹ̀ sápá òsì.

Nígbà  míràn, a máa ṣe àfihàn ipò láwùjọ nípa bí o ti wọ́n lówó ju-ra-wọn-lọ.

lásìkò yìí, gèlè Aṣọ-òkè ni o gbàgbooro, kìí si ṣe yaayaa púpọ̀, síbẹ̀-síbẹ̀, a lèè ṣe lẹ́ṣọ, ṣe e lárà lórísirísi láti jẹ́ kí ó tún bọ̀ jẹ ojú ní gbèsè.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Iwalaiye, Temi (2021-11-17). "The significance of a gele in traditional attires". Pulse Nigeria. Retrieved 2023-02-20. 
  2. Iwalaiye, Temi (2021-11-17). "The significance of a gele in traditional attires". Pulse Nigeria. Retrieved 2023-02-20. 
  3. Temi Iwalaiye. The significance of a Gele in traditional attires. November 17,2021.