Gbólóhùn Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

'Gbólóhùn èdè Yorùbá ni a lè pè ní odidi ọ̀rọ̀ tí ó pé, tí ó ní olùṣe ati abọ̀ nínú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú lẹ́tà ńlá. Síńtáàsì ni èka kan nínú gírámà èdè tí ó níí sè pèlú bi a se ń so òrò pò tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Síntáàsì ní òfin ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yí yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun ti elédè so jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón eléyìi kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn làákàyè elédè sá féré bóyá látaàrí òhún jíje tàbí mįmu ti ó le máa mú elédè so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti opolo red bá padà sípò, yóò so òrò ti ó mógbón lówó.

Òfin Síntáàsì[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan. Fún àpeere, eni tí ó bá gbó èdè Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà,

(1) (a) Mo lo sí oko

(b) Sí lo oko mo

Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nipé ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò tí yóò first di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu. O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin bíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé ítéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé ìtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé.

(2) (a) Àwon ti ó lo kò pò

(b) Àwon ti wón lo kò pò

Méjèèjì ni ó bófin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé ìtéwógbà, èkejì kò jé ìtéwógbà. Èyí kò ni ǹ kan se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófin mu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú jùlo.

Èdè gégé bí àdámó[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó ye kí á mò wípé òhún àdámó ni èdè jé. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó bí Wón tí ń so Èdè abínibí rè. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àdámó ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè abínibí, ó ti wà lára rè. Kò sí èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. (2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a ba tòó pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b).

(3) (a) Olú gíga lo

(b) Olú lo

Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye.

Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere:

(4) GB ---> APOR APIS

Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5).

(5) GB ---> APOR AF APIS

Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí:

(6) AF ---> AS, IB, M, IBM

Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS