Gbẹ̀du

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Gbedu Drum

GBẸ̀DU:-


Pàtàkì ni Gbẹdu jẹ̀ nínú àwọn ìlù ìbílẹ̀ Yorùbá. Ìlù yii kan naa lawọn kan n pen i àgbà. Ìyàńgèdè ni ìlẹ̀ Yorùbá.

Ìlù mẹta la le tọkasi nínú ọwọ ìlù Gbẹ̀du.

(a) Aféré:- Ìlù nla ni afẹrẹ. Ó ga tó iwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rin ó sì gùn gbọọgì. Géńdé ti ko ba dara rẹ loju ko le gbe nìlẹ. Oùn rẹ̀ máa n rìnlẹ dòdò. Ìkeke ni a fi maa nlù.

(b) Apéré tabi Opéré: Ìlù yii lo tobi tẹle afẹrẹ labẹ ọmọ ìlù ti a n pe ni Gbẹdu. Igi la fi gbẹẹ, ṣùgbọ́n ko ga, ko si fẹ lẹnu to aféré.

(d) Ọbadan: Ìlù yii lo kere ju nínú ọ̀wọ́ ìlù Gbẹdu. Igi la fi gbẹẹ bi ti awọn yooku. Ko sit obi to apẹẹrẹ rara.

Gbẹdu se patakì pupọ nitori pe o jẹ ìlù ọba. A kii dede n lu u. Ìlù yi wa fun ìyẹ̀sì awọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá. Bi ọba ba gbesẹ tabi ijoye nla kan tẹri gbaso wọn n lù Gbẹdu lati fi tufọ.