Gemma Chan

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Gemma Chan jẹ́ òṣeré sinimá àgbéléwò ọmọ orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ipa tí ó kó nínú sinimá àgbéléwò kan tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ Crazy Rich Asians lọ́dún 2018 ló sọ ó di gbajúmọ̀ òṣèré ìlúmọ̀ọ́kà káàkiri gbogbo àgbáyé. [1] [2] [3]

Ìgbé-ayé rẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Gemma Chan sì ìlú London ṣùgbọ́n ó dàgbà sí ìlú Kent. Ó kàwé ní ilé ìwé àwọn obìnrin Newstead Wood School for Girls, ó sìn tún lọ kẹ́kọ̀ọ́ gíga ní Worcester College, ní ìlú Oxford, ibẹ̀ gboyè nípa ìmọ̀ òfin. Bí ó ti jẹ́ amọ̀fin tó, kò fi ṣiṣẹ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ó fara mọ́ iṣẹ́ èrè sinimá àgbéléwò lẹ́yìn tí ó tún kẹ́kọ̀ọ́ si ní ilé ìwé Drama Centre ní London. Ó wà nínú onírúurú ère orí ẹ̀rọ amóhùnmàwòrán bíi Doctor Who special "The Waters of Mars", Secret Diary of a Call Girl (2011), Fresh Meat (2011) àti Bedlam (2011). Ọ̀pọ̀lọpọ̀ erè sinimá àgbéléwò ló ti kópa tí ó sì tún gba àmìn ẹ̀yẹ lóríṣiríṣi.[4] [5]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Gemma Chan on Twitter". Twitter (in Èdè Latini). 2019-11-05. Retrieved 2019-11-25. 
  2. Randall, Lee (2012-05-27). "Interview: Gemma Chan, star of True Love". The Scotsman. Retrieved 2019-11-25. 
  3. Kroll, Justin (2019-08-05). "Gemma Chan in Talks to Join Marvel’s ‘The Eternals’ (EXCLUSIVE)". Variety. Retrieved 2019-11-25. 
  4. "Empire". Empire. 2015-08-15. Retrieved 2019-11-25. 
  5. Nicholson, Rebecca (2019-07-28). "Gemma Chan: ‘Nothing will top the night I pole-danced with Celine Dion on a bus’". the Guardian. Retrieved 2019-11-25.