Jump to content

Gírámà Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Girama Yoruba)

Gírámà èdè Yorùbá

Gírámà ni ìmò nípa bí a ṣe ń lọ àwọn ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ètò àti ìlànà ni èdè Yorùbá

Ìsòrí gírámà ni wọn yìí

(a) Ọ̀rọ̀ orúkọ

(b) Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ orúkọ

(d) Ọ̀rọ̀ arọ́pọ̀ afarajorúkọ

(e) Ọ̀rọ̀ ìṣe

(ẹ) Ọ̀rọ̀ àpèjúwe

(f) Ọ̀rọ̀ àpọ́nlé

(g) Ọ̀rọ̀ atọ́kùn

(gb) Ọ̀rọ̀ àsopọ̀.[1]

Girama Yoruba

Kí ni Sińtáàsì? Síńtáàsì jẹ́ ọ̀kan lára ẹ̀ka gírámà èdè tí ó ní í sè pèlú bi a se ń so òrò pọ̀ tí ó fi ń di gbólóhùn àti bí a se ń fún gbólóhùn yìi ní ìtumò. Nínú ìdánilékòó yìi, a ó máa m ẹ́nu ba ohun tí a ń pè ni òfin. Ìtumò òfin gégé bí a se lò ó ni àwon ìlànà ti elédè máa ń tèlé nígbà tí ó bá ń so èdè rè yii yàtò si ìlò èdè. Ìmò èdè ni ohun tí elédè mò nípa èdè rè sùgbón ìlò èdè ni ohun tí elédè sọ jáde ní enu. Elédè lè se àsìse nípa ìlò èdè sùgbón èyí kò so pé elédè yìí kò mo èdè rè. Òpò ìgbà ni ènìyàn lè mu emu yó ti yóò máa so kántankàntan. Kì í se pé elédé yìí kò mo èdè rè mo, ó mò ón. Àsìse ìlò èdè ni ó ń se. Nìgbà ti otí bá dá ní ojú rè, yóò sọ òrò ti ó mógbón lówó. Nínú ìdánilékòó yìí, a ó ménuba ohun tí a ó pè ní ofin. Ohun tí a pè ni òfin yìí ni bi elédè se ń so èdè rè bí ìgbà pé ó ń tèlé ìlànà kan.bí àpẹẹrẹ re, eni tí ó bá gbó Yorùbá dáradára yóò mò pé (1a) ni ó tònà pe (1b) kò tònà,

(1) (a) Mo lo sí oko

(b) Sí lo oko mo

Ohun tí eléyìí ń fi hàn wá nipé ìlànà kan wà tí elédè ń tèlé láti so òrò pò di gbólóhùn. Irú gbólóhùn tí ó bá tèlé ìlànà tí elédè mò yìí ni a ó so pé ó bá òfin mu.

O ye kì a tètè menu ba ìyàtò kan ti ó wà láàrin tíbá òfin mù àti jíjé àtéwógbà. Gbólóhùn lè wà ti yóò bá òfin mu sùgbon tí ó lè máà jé àtéwógbà fún àwon tí ń so èdè. Bíbófinmu níí se pèlú ìmò èdè; ìlò èdè ni jíjé àtéwógbà níí se pèlú. Fún àpeere, àwon kan lè so pé (2a) kò jé àtéwógbà fún àwon wi pé (2b) ni àwon gbà wolé.

(2) (a) Àwon ti ó lo kò pò

(b) Àwon ti wón lo kò pò

Méjèèjì ni ó bá òfin mu nítorí méjèèjì ni a máa ń so nínú èdè Yorùbá. Ìyen ni pé méjèèjì ni ó wà nínú ìmò wa gégé bí eni tí ó gbó Yorùbá. Nínú ìlò ni àwon kan ti lè so pé òkan jé àtéwógbà, èkejì kò jé àtéwógbà. Èyé kò ni nǹken kan án se pèlú pé bóyá gbólóhùn méjèèjì bófin mu tàbí won kò bófinmu. Ìmò elédè nípa èdè rè ni yóò je wá lógún nínú ìdánilékòó yìí.

Ó ye kí á tún pe àkíyèsí wa sí tip é àbínibí ni èdè o. Ènìkan kì í lo sí ilé-ìwé láti kó ọ. Ohun tí a ń so ni pé bí ìrìn rinrìn se jé àbìnibì fún omo, béè náà ni èdè jé. Fún àpeere, tí kò bá sí ohun tí ó se omo, tí ó bá tó àkókò láti rìn yóò rìn. Kì í se pé enì kan pe omo gúnlè láti kó o ni èyi. Báyìi gélé náà ni èdè jé. Àbínibí ni gbogbo ohun ti omo nílò fún èdè, ó ti wà lára re. Kò sì si èdè ti kò lè lo èyí fún sùgbón èdè ibi tí a bá bi omo sì ni yóò lo àwon ohun èlò yìí láti so. (2) Òrò àti Àpólà: Òrò ti a bat ò pò ni ó ń di àpólà. Ó seé se kí àpólà jé òrò kansoso. Ìyen tí òrò yìí kò bá ní èyán. Fún àpeere, àpólà-orúko ni a fa igi sí ní ìdi ní (3a) àti (3b).

(3) (a) Olú gíga lo

(b) Olú lo

Ìyàtò àpólà-orúko méjèèjì yìí ni pé òrò méjì ni ó wa nínú àpólà-orúko (APOR’ ni a ó má a pè é láti ìsinsìnyí lo) (3a); òrò-orúko àti èyán rè tí ó jé òrò-àpèjúwe (AJ ni a ó máa pe òrò-àpèjúwe). Ní (3b), òrò kansoso ni ó wà lábé APOR. Òrò yìí, òrò-orúko (OR ni a ó máa lò fún òrò-orúko) ni, APOR náà sì ni. Ìsòri-òrò méjo ni àwon tètèdé onígìrámà so pé ó wà nínú èdè Yorùbá. Ìsòrí òrò méjo yìí ni wón sì pín si Olùwà àti Kókó Gbólóhùn. Olùwà àti kókó gbólóhùn yìí ni àwa yóò máa pè ní APOR àti APIS (àpólà-ìse) nínú ìdánilékòó yìí. Ìyen nip é àwa yóò ya ìsòrì-òrò àti isé ti ìsòri yìí ń se sótò si ara won. Ìsòri ni APOR tí ó ń sisé olùwà tàbí àbò nínú gbólóhùn. Ìsòrí ni APIS ti ó ń sisé kókó gbólóhùn. 3. Gírámà ti a ó lò: Gírámà ìyidà onídàro ti Chomsky ni a ó mú lò nínú isé yìí. Ohun tí ó fà á ti a ó fi mú gíràmà yìí lò nip é ó gbìyànjú láti sàlàyé ìmò àbinibí elédè nípa èdè rè. Gírámà yìí sàlàyé gbólóhùn oónna, gbólóhùn ti ó jé àdàpè ara won abbl. Gírámà yìí yóò lo òfin ti ó níye láti sàlàyé gbólóhùn tí kò niye.

Àwon àmì kan wà ti a ó mú lò nínú gírámà yìí. Fún àpeere:

(4) GB ---> APOR APIS

Òfin ìhun gbólóhùn ni a ń pe (4). Ohun tí àmì òfà yìí ń so ni pé kí á tún gbólóhùn (GB) ko ni APOR àti APIS. Ó ye kì á tètè so báyìí pé ohun tí ó wà nínú gbólógùn ju èyí lo. Ohun tí a máa ń rí nínú gbólóhùn gan-an ni (5).

(5) GB ---> APOR AF APIS

Àfòmó ni AF dúró fún. Òun ni a máa ń pè ní àsèrànwò-ìse télè. Abé rè ni a ti máa ń rí ibá (IB), àsìkò (AS), múùdù (M) àti ìbámu (IBM). A lè fi èyí hàn báyìí:

(6) AF ---> AS, IB, M, IBM

Kì í se dandan kí èdè kan ní gbogbo mérèèrin yìí. Yorùbá kò ni àsìkò sùgbón ó ni ibá. A ó menu ba àfòmó dáadáa ní iwájú sùgbón kí a tó se èyí, e jé kí á sòrò nípa APOR àti APIS

Ayọ Bámgbóṣé

Gìrámà

Fonoloji ati Girama Yoruba

Ayọ̀ Bámgbóṣé (1990), fonọ́lọ́jí àti Gírámà Yorùbá. Ìbàdàn, Nigeria: University Press Limited. ISBN 978 249155 1. 239 pp.

Ọ̀RỌ̀ ÀKỌ́SỌ

Láti ìgbà tí Ìgbìmọ̀ Ìwádìí Ìjìnlẹ̀ Ẹ̀kọ́ (N.E.R.C.) ti gbé ìlànà ẹ̀kọ́ Yorúbá fún ìlò -ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì jáde ni ó ti di dandan láti wá ìwé tí yó ṣe àlàyé yékéyéké lórí àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ yọ nínú ìlànà ẹ̀kọ́ tuntun yìí. Ìrírí wa nipé àti akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ni ó máa ń ni ìṣòro lórí iṣẹ́ tí ó bá èdè yàtọ̀ sí lítíréṣọ̀. lọ Ìdí nìyí tí a fi ṣe ìwé yìí lórí èdè, tí a sì lo ìmọ̀ ẹ̀dà-èdè láti fi ṣàlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ fonọ́lọ́jì àti gíràmà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ Sẹ́kọ́ńdírì àti ti olùkọ́ni, láìmẹ́nuba àwọn olùkọ́ ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀, ni wọ́n ti ń lo ìwé Èdè Ìperí Yorùbá tí N.E.R.C. tẹ̀ jáde ní ọdún 1984, tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Ayọ̀ Bámgbóṣé sì ṣe olótùú rẹ̀. ìwé Fonọ́lọ́jì àti Gírámà Yorùbá yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ kejì lórí lílo èdè-ìperí Yorùbá nítorí pé a ṣe àlàyé àwọn èdè-ìperí tí ó bá ẹ̀dá-èdè lọ dáadáa; a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìtumọ̀ wọn hàn kedere. Nípa lílo ìwé yìí, èdè-ìperí á kúrò ní àkọ́sórí nìkan: kódà, á á di ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ mọ̀ dénú, tí wọ́n sì lè ṣàlàyé rẹ̀ fún ẹlòmíràn.

Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi tí mo ṣe Olóòtú ìwé Èdè-Ìperí Yorùbá náà ni mo kọ ìwé tuntun yìí. Mo sì kọ ọ́ ní ọ̀nà tí yó rọrùn fún akẹ́kọ̀ọ́ láti kà nítorí pé nípa ìrírí púpọ̀ tí mo tin í nípa kíkọ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀dá-èdè Yorùbá, mo mọ ọgbọ́n tí a lè fi ṣe àlàyé àwọn orí-ọ̀rọ̀ tí ó díjú lọ́nà tí yó lè fi tètè yé ni.

A dá ìwé yìí sí ọ̀nà mẹ́ta. Apá kìíni ni Fonọ́lọ́jì, Apá kejì ni Gírámà. Apá kẹta sì ni Ìdánwò Èwonìdáhùn. Nínú apé kìíní àti apá kejì, a pín àwọn orí-ọ̀rọ̀ sí abẹ́ orí kọ̀ọ̀kan nínú èyí tí a ṣe àlàyé àti ìtúpalẹ̀ orí-ọ̀rọ̀, tí a sì lo àpẹẹrẹ oríṣiríṣi láti fi ìdí ìtúpalẹ̀ náà gúnlẹ̀ dàadáa. Lẹ́yìn èyí ni a fi ìdánrawò kádìí orí kọ̀ọ̀kan. Orí mẹ́rìnlá ni ó wà ní abẹ́ Fonọ́lọ́jì, tí méjìdínlógún sì wà lábẹ̀ Gírámà. Ó ṣeé ṣe fún olùkọ́ láti fa ẹ̀kọ́ méjì mẹ́ta yọ láti ara ori kọ̀ọ̀kan. A sì tún lè lo orí kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí a ti ṣe kọjá lorí orí-ọ̀rọ̀. Ní apá kẹta ìwé yìí, a fi ìdánwò èwonìdáhùn mẹ́rin nínú èyí tí ìbéèrè méẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n wà nínú ìkọ̀ọ̀ken ṣe àpẹẹrẹ irú ibéèrè ti a lè ṣe fún gírámà àti fonọ́lọ́jì Yorùbá. Irú àpẹẹrẹ ìdánwò báyìí yóò wúlò fún àwọn tí ó ń sẹ́ẹ̀tì ìdánwò àti fún àwọn olùkọ́ pẹ̀lú. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pàápàá yó lè lo ìdánwò yìí gẹ́gẹ́ bí àfikún fún ìdánrawò tí ó wà lẹ́yìn orí kọ̀ọ̀kan.

Mo ké sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ láti ran ara wọn lọ́wọ́ nínú ẹ̀kó Yorùbá. Ọ̀nà tí wọ́n sì lè fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni kí wọn lo ìwé tí yó mú kí ẹ̀kọ́ Yorùbá rọrùn fún wọn láti kọ́. Ìwé tí ó lè ṣe èyí ni ìwé tuntun yìí. Ìwé náà sì lè fún wọn ní ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún ẹ̀kọ́ Yorùbá ní ilé-ẹ̀kọ́ gíga.[2]

Àwọn Ìtọ̀ká sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "ESSENTIALS OF YORUBA GRAMMAR By Oladele Awobuluyi". Sunshine Bookseller. Archived from the original on 2020-03-27. Retrieved 2020-03-27. 
  2. "Essentials Yoruba Grammar by Oladele Awobuluyi". AbeBooks. 1982-12-29. Retrieved 2020-03-27.