Godwin Babátúnde Kofi Akran

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Godwin Babatunde Kofi Akran A bí Ọba Akran ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹ́sàn-án ọdún 1936. Ó lọ sí Salvation Army School, Kakawa, Lagos láàrin 1946 sí 1947, Methodist School, Badagry àti Methodist Teachers Training College, Ìfàkì-Èkìtì láàrin 1956 sí 1957. Ó lọ sí International Press Institute, University of East Africa, Nairobi, Kenya ní 1977. Ó di reporter fún West African Plot ní 1961, News Editor, New Nigerian Newspapers 1975-1977. Ó di Ọba ìlú Badagry gẹ́gẹ́ bíi De Whenọ Ahọlu Mẹnu Toyi 1 ní ọdún 1977.