Jump to content

Hadiza Lantana Oboh

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Hadiza Lantana Oboh (ọdún 1959 sí 1998) jẹ́ awakọ̀ ojú òfuurufú ọmọ-orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Òun nìkan ni obìnrin tí ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bi awakọ̀ ojú òfuurufú fún ilé ìṣẹ́ Nigeria Airways.[1] Wọ́n ṣekú pá ní ọjọ́ kẹjọ oṣù kejì ọdún 1998, àwọn afunrasí nínú ọ̀rọ̀ náà jẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ nínú ilé rẹ̀ tí wón jà lólè.[2][3]

Oboh ti ń wa ọkọ̀ òfuurufú fún ilé ìṣe míràn fún ọ̀pọ̀ ọdún kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ fún ilé isẹ́ Nigeria Airways.[4]

Hadiza Lantana Oboh jẹ́ ọmọ ọdún kàndínlógójì nígbà tí wọ́n ṣekú pá.[2] Àwọn ọlọ́pá rí òkú rẹ̀ ní ihò tí wón da ìgbẹ́ sí lẹ́yìn tí wọ́n ká atọjú ọgbà rẹ̀ níbi tí ó ti ń gbìyànjú láti ta àwọn ǹkan ìní Hadiza. Àwọn ọlọ́pá gbé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ilé Hadiza kí wọ́n tó fi wọ́nlẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Àwọn òṣìṣẹ́ yí ṣálọ.[2][3]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Ijeoma Thomas-Odia, Celebrating ‘First Ladies’ of the professions Archived 2023-05-28 at the Wayback Machine., The Guardian, 23 March 2019. Accessed 16 May 2020.
  2. 2.0 2.1 2.2 Jo Daniel, The Tragic Story Of Captain Hadiza Lantana Oboh, Nigeria Airways’ First & Only Female Pilot, Information Nigeria, 20 June 2015. Accessed 16 May 2020.
  3. 3.0 3.1 Late Hadiza Lantana Oboh: Ex-Nigerian Airways pilot murdered in cold blood Archived 2020-06-15 at the Wayback Machine., Nigerian Flight Deck, 11 September 2016. Accessed 16 May 2020.
  4. West Africa, 1989, p.1922