Hafizur Rahman Wasif Dehlavi

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Mawlānā, Mufti

Hafizur Rahman Wasif Dehlavi
4th Rector of Madrasa Aminia
In office
September 1955 – 1979
AsíwájúAhmad Saeed Dehlavi
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí(1910-02-10)10 Oṣù Kejì 1910
Shahjahanpur, British India
Aláìsí1987
Delhi, India
BàbáKifayatullah Dehlawi
Alma materMadrasa Aminia

Hafizur Rahman Wasif Dehlavi (Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù Kejì, Ọdún 1910 – Ọjọ́ Kẹtàlá, Oṣù Kẹ̀ta, Ọdún 1987) jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Índíà, Ọ̀jọ̀gbọ́n lórí Ìmọ̀ Mùsùlùmí, Agbẹjọ́rò, Lámèyítọ́ iṣẹ́-ọnà lítíréṣọ̀, àti Akéwì èdè Urdu, Ó sì tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Olùdarí ilé kéwú kan tí ó ń jẹ́ Madrasa Aminia láti ọdún 1955 sí ọdún 1979. Ó kópa nínú ìjà fún òmìnira orílẹ̀ èdè India, Ó jẹ̀ tún kọ àwọn ìwé bíi Adabī bhūl bhulayyān̲, Urdū Masdar Nāmā àti Taz̲kirah-yi Sā'il. Ó tún ṣe àkójọpọ̀ iṣẹ́ bàbá rè lórí ẹ̀sìn láti Kifayatullah Dehlawi sí Kifāyat al-Mufti lọ́nà mẹ́sàn-án ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀[1][2].

Ìtan Ìgbèsi Àye Hafizur Rahman[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Hafizur Rahman Wasif Dehlavi jẹ́ ọmọ tí wọ́n bí ní Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù Kejì, Ọdún 1910 ni Shahjahanpur.[3] Òun ni Àkọ́bí Kifayatullah Dehlawi, tó jẹ́ olùdarí àwọn Mùsùlùmí ní orílẹ̀ èdè India.[3] Ilé kéwú tí ó ń jẹ́ Madrasa Aminia ní ó lọ pẹ̀lú bàbá rẹ̀ Kifayatullah Dehlawi àti àwọn ọ̀mọ̀wé mìíràn bíi Khuda Bakhsh àti Abdul Ghafoor Aarif Dehalvi. Ó kọ́ bí wọn ṣe ń kọ kéwú pẹ̀lú Hamid Hussain Faridabadi àti Munshi Abdul Ghani..[4]

Wasif bẹ̀rẹ iṣẹ rẹ gẹ̀gẹ̀bi ólukọ ti ede larubawa ati litirèṣọ ni ilè ẹ̀kọ ti Ijọba ni Delhi[5]. Ni ọdun 1936, Baba rẹ̀ fi jẹ óludari ti Kutub Khana Rahimiya. Arakunrin naa kopa ninu ijàgbàra óminira ilẹ India to si ku ni ọjọ mẹtala, óṣu March, ọdun 1987 ni Delhi[6][7].

Awọn Ìṣẹ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wasif ṣè akójọpọ iwè ẹsin ti baba rẹ Kifayatullah Dehlawi pẹlu akọlè Kifāyat al-Mufti ni iwọ didun mẹsan [8] ónimọ itan Abu Salman Shahjahanpuri pè iṣẹ yii ni ti ẹkọ, ẹsin ati ti Óṣèlu [3] Awọn iṣẹ Wasif to ṣẹ ky:[8]

  • Adabī bhūl bhulayyān̲: zabān-o-qawā'id aur Urdū imlā par tanqīd
  • Jamī'at-i Ulamā par ek tārīk̲h̲ī tabṣirah
  • Sih lisānī Masdar Nāmā
  • Taz̲kirah-yi Sā'il
  • Urdū Masdar Nāmā
  • Zar-i gul

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Aliyah, Zainab (2022-02-10). "On This Day In Muslim History: February 10". The Cognate. Retrieved 2023-09-15. 
  2. Vincent, Maria (2021-07-22). "Important Freedom Fighters of India – List, Role, Biography". Entri Blog. Retrieved 2023-09-15. 
  3. 3.0 3.1 3.2 Shahjahanpuri 2005, pp. 105-106.
  4. Adrawi 2016, p. 82.
  5. Dehlavi 2011, p. 24.
  6. Dehlavi 2011, p. 28.
  7. Amini 2017, p. 185.
  8. 8.0 8.1 Amini 2017, pp. 210-211.