Jump to content

Henry Fajemirokun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Henrry Fajemirokun)
Henry Oloyede Fajemirokun
GCON
Ọjọ́ìbí(1926-07-26)Oṣù Keje 26, 1926
Ile-Oluji, Ondo State, Nigeria
AláìsíFebruary 15, 1978(1978-02-15) (ọmọ ọdún 51)
Abidjan, Côte d'Ivoire
Orúkọ mírànChief Fajemirokun
Iṣẹ́Businessman
Gbajúmọ̀ fúnHenry Stephens, Rank Xerox Nigeria, Nigerian-American Merchant Bank, ECOWAS

Henry Oloyede Fajemirokun, CON Jẹ́ ògbóǹtarigì oníṣòwò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n bí i ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù kéje, Ọdún 1926. Ó sì kú ní ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì, ọdún 1978. Òun pẹ̀lú Adebayo Adedeji ní ìgbàgbọ́ nínú ètò-ọrọ̀-ajẹ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ti ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà [1][2] èyí tí ó di ohun tí à ń pè ní Economic Community of West African States (ECOWAS).

Ó rí ìdí fún ilé-iṣẹ́ aládàáni láti wà, ó sì pèsè àwọn ilé-iṣẹ́ aládàáni. Ó mú kí àwọn iriṣẹ́ tí ètò-ọrọ̀-ajẹ́ nílò ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà, àti commonwealth gbèrú sí i.

Ó jẹ́ olórí ẹlẹ́ẹ̀kẹ́rin ti Nigerian Association of Chambers of Commerce, Industry, Mines and Agriculture (NACCIMA) Archived 28 August 2018 at the Wayback Machine., Olórí ẹlẹ́ẹ̀kẹfà ti Lagos Chamber of Commerce and Industry, olórí àkọ́kọ́ ti Federation of West African Chambers of Commerce Archived 19 January 2023 at the Wayback Machine. (1972–1978) àti olórí olùdásílẹ̀ Nigerian-British Chamber of Commerce Archived 2 November 2017 at the Wayback Machine. (NBCC) pẹ̀lú Sir Adam Thomson,[3][4] alága British Caledonian Airways èyí tí ó wà lára British Airways). ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà àti olórí tẹ́lẹ̀ rí ní Nigerian-American Chamber of Commerce (NACC). Bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ olórí fún, Federation of Commonwealth Chambers of Commerce.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀.

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ile Oluji, ní ìpínlẹ̀ Ondo ni wọ́n bí Henrry sí. Màmá rẹ̀ jẹ́ ọmọ olóyè ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Odofin Oganbule Akinsuroju.

Ilé-ìwé St.Peter's, ní Ile-Oluji àti ilé-ìwé tí orúkọ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ jẹ́ St Luke's, Oke-igbo ni ó ti ka ìwé mẹfà rẹ̀. Ó ka ìwé mẹ́wàá rẹ̀ ní CMS Grammar School, Lagos àti ní Ondo Boys High School (1942–1944). Lẹ́yìn tó parí ìwé rẹ̀ ní Ondo Boys school, Ó darapọ̀ mọ́ Royal West African Frontier Force ní ọmọ ọdún méjìdílógún. Ó sì si ìlú ní ilẹ̀ India ní àsìkò ogun àgbáyé kejì. Lẹ́yìn ogun náà ni ó darapọ̀ mọ́ ẹ̀ka Post and Telegraph Department gẹ́gẹ́ bí i òṣìṣẹ́ , ó sì kàwé ní ìkọ̀kọ̀ fún ìwé-èrí ilé-ẹ̀kọ́ Cambridge.[5][6]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Adebajo, Adekeye; Rashid, Ismail O. D. (2004). West Africa's Security Challenges: Building Peace in a Troubled Region. Lynne Rienner Publishers. p. 31. ISBN 978-1-58826-284-4. https://books.google.com/books?id=9cejA35XvBgC&pg=PA31. 
  2. Akinyeye, Yomi (2010). Nation-states and the Challenges of Regional Integration in West Africa: The Case of Nigeria. KARTHALA Editions. p. 52. ISBN 978-2-8111-0338-5. https://books.google.com/books?id=SZ-SmUs9pUEC&pg=PA52. 
  3. Cowe, Roger (2000-05-31). "Sir Adam Thomson" (in en-GB). The Guardian. ISSN 0261-3077. https://www.theguardian.com/news/2000/jun/01/guardianobituaries.rogercowe. 
  4. "Sir Adam Thomson, b. 1926. Founder and chairman of British Caledonian Airways". www.nationalgalleries.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2017-07-29. 
  5. Forrest, Tom G. (1994). The Advance of African Capital: The Growth of Nigerian Private Enterprise. University of Virginia Press. p. 95. ISBN 978-0-8139-1562-3. https://books.google.com/books?id=xfHsJMBLWlsC&pg=PA95. 
  6. Odunfa, Sola (October 1975). "Kng Henry". Spear Magazine.