Hilarie Burton
Ìrísí
Hilarie Burton | |
---|---|
Burton ní ọdún 2016 | |
Ọjọ́ìbí | 1 Oṣù Keje 1982 Sterling, Virginia, U.S. |
Orúkọ míràn | Hilarie Burton Morgan |
Iléẹ̀kọ́ gíga | New York University Fordham University |
Iṣẹ́ | Actress, producer, television host |
Ìgbà iṣẹ́ | 1997–present |
Olólùfẹ́ | Jeffrey Dean Morgan (m. 2019) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Hilarie Ros Burton (tí a bí ní ọjọ́ kínní oṣù keje ọdún 1982),[1] tí àwọn mìíràn mọ̀ sí Hilarie Burton Morgan, jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó ti fi ìgbàkan jẹ́ olótùú fún ètò MTV tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Total Request Live, ó ṣeré gẹ́gẹ́ bi Peyton Sawyer nínú eré WB àti CW tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ One Tree Hill (2003–2009). Lẹ́yìn One Tree Hill, Burton ṣeré nínú Our Very Own, Solstice, àti The List. Ó tún kó ipa Sara Ellis nínú eré White Collar (2010–2013), Dr. Lauren Boswell nínú ABC medical drama Grey's Anatomy (2013), Molly Dawes nínú eré ABC pẹ̀lú àkọ́lé Forever (2014), àti gẹ́gẹ́ bi Karen Palmer nínú Fox, bákan náà ó farahàn nínú Lethal Weapon (2016). Burton jẹ́ ara àwọn olóòtú ètò Drama Queens òun pẹ̀lú Sophia Bush àti Bethany Joy Lenz.