I Told You So (fíìmù 1970)
Ìrísí
I Told You So jẹ́ fíìmù orílẹ̀-èdè Ghana tó jáde ní ọdún 1970. Fíìmù náà ṣàfihàn àwọn ará Ghana àti ọ̀nà ìgbà wọ aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ sì ni ó fún wa ní òye ìgbésí-ayé ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí kò gbọ́ràn sí àmọ̀ràn bàbá rẹ pé kí ó má fẹ́ arákùnrin kan nítorí kò mọ nǹkan kan nípa arákùnrin náà tó fẹ́ fẹ́. Àmọ́ ọ̀dọ́mọbìnrin yìí gba ìmọ̀ràn ìyá rẹ̀ àti àbúrò ìyá rẹ̀, nítorí ọrọ̀ tí arákùnrin náà ní, àti irú ìdílé ọlọ́lá tí arákùnrin náà ti wá.
Ọ̀dọ́bìnrin náà wá rí i pé ọkùnrin tó yẹ kóun fẹ́ jẹ́ ọlọ́ṣà tó ní ìhámọ́ra . Inú rẹ̀ kò dùn sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Nígbà tí bàbá rẹ̀ béèrè ohun tó ṣẹlẹ̀, ó fèsì pé ọkùnrin tó yẹ kóun fẹ́ jẹ́ ọlọ́ṣà; bàbá rẹ̀ parí ọ̀rọ̀ náà nípa síso pé "Mo sọ fún ọ bẹ́ẹ̀".[1][2][3]
Àwọn òṣèrẹ́ tó kópa
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Bobe Cole
- Margret Quainoo[4] (Araba Stamp)
- Kweku Crankson (Osuo Abrobor)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Kofi, Nana. "I Told You So returns in August". Citifmonline.com. Nana Kofi. Retrieved 6 November 2018.
- ↑ Sharparrows. "I Told You So (1970): A Ghanaian Film Noir". Ghana film industry. Sharparrows. Archived from the original on 27 November 2020. Retrieved 6 November 2018.
- ↑ "I told You So to play at Conference Centre - Graphic Online". www.graphic.com.gh (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2020-08-06.
- ↑ Empty citation (help)