Jump to content

Ibùdó Ogunléndé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ibùdó Ogunléndé jẹ́ ibùdó pàjáwìrì tí wọ́n kọ́ láti pèsè ilé, àbọ̀, oúnjẹ, ìlera àti àwọn nǹkan mìíràn fún àwọn tí ó móríbọ́ ní agbègbè, ìlú tàbí orílẹ̀ èdè tí ogun ń jà tàbí tí wàhálà kan bẹ́ sílẹ̀ sí. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ó lè máà jẹ́ ogún, kí ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá pàjáwìrì bíi, ìjì búburú, iná, ìṣẹ̀lẹ̀ ẹṣin-ò-kọkú àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tàbí ìjàm̀bá búburú mìíràn ni wọ́n ṣe máa ń dá ibùdó Ogunléndé sílẹ̀.[1] [2]

Àwọn tí wọ́n máa ń dá Ibùdó Ogunléndé sílẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìjọba orílẹ̀ èdè, ìpínlẹ̀, ajo àgbáyé tàbí àjọ tó da orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè pọ̀, àjọ aṣèrànlọ́wọ́-ọ̀fẹ́ tí kìí ṣe ti ìjọba ló máa ń dá ibùdó Ogunléndé sílẹ̀ láti dá àbò bo àwọn tí ogún tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá lé kúrò nílé tàbí orílẹ̀-èdè wọn.[3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "What is a Refugee Camp? Definition and Statistics". USA for UNHCR. Retrieved 2019-11-23. 
  2. "Refugees". United Nations. 2015-12-14. Retrieved 2019-11-23. 
  3. Commissioner, United Nations High. "Saving lives at the world's largest refugee camp". UNHCR. Retrieved 2019-11-23. 
  4. "How to Build a Perfect Refugee Camp - The New York Times". Google. 2014-02-16. Retrieved 2019-11-23.