Igbo Biseni

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àdàkọ:Infobox forest

Igbó Biseni igbó omi tàbí igbó irà tí ó fìkàlẹ̀ láàárín ìlú Ahoada àti apá òkè igbó Orashi ní agbègbè Niger Delta.[1] Igbó náà tóbi tó ìwọ̀n kìlómítà 219 ní ìbú àti Òró tí ó kún fún ilẹ̀ omi.[1][2]

Àwọn koríko rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Igbó Biseni jẹ́ inú irà tí ó kún fún àwọn igi gẹdú àti àwọn koríko mìíràn tí wọ́n sáàbà máa ń gbẹ lásìkò ẹrùn tí ó sì máa ń kún fún omi rọ́rọ́ nígbà òjò. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Igi agbe àti àwọn igi mìíràn tí wọ́n fẹ́ràn omi ni wọ́n wọ́pọ̀ nínú igbó Biseni. Bákan náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn koríko omi bíi òṣíbàtà àti àwọn koríko mìíràn ló kún fọnfọn sí ibẹ̀, pàápàá jùlọ lẹ́bàá igbó náà.[2]

Àwọn ẹranko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Igbó Biseni kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹyẹ àti àwọn ẹranko-afọ́mọlọ́yàn tí wọ́n ṣọ̀wọ́n.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

]