Jump to content

Ìgè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ige)

Opadotun

Olátúnjí Ọ̀pádọ̀tun

Ewì Fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ìwé Kejì

Ige

Ìgé Adùbí ìsa

Àdùbí oníkẹ̀ẹ́yẹ

Ẹni ti kò màdùbí

A lóníkẹ̀ẹ́yẹ̀ ṣánpọ́nná

Iké ṣeé yẹ̀ lẹ́yìn ẹni

Ìgè Àdùbí asaare

Èèyàn tó bẹ Ìgè Àdùbí níṣẹ́

Ojo


Òjó olúkù-lóyè

Igbe kíké níṣẹ́ ẹyẹ

Òjó Àdìó alájòóòsinmi

Tóo jó láruru

Tóo sì jó ní kọ̀bì

Ajayi

Àjàyí Ògídí olú

Oníkánga àjípọn

Ò bomi òsùùrù wẹdà

Ẹni Àjàyí gbà gbà tí ò le gbà tán

Aríléwọ́lá, ikú ní í gbolúwarẹ

Irele

Àwọn ewí àkàkọ́gbọ́n: Ìrẹ̀lẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Títí tí n ó fi kú

N ò ní yéé hùwà ìrẹ̀lẹ̀

N ò ní rágbà fún

N ò ní lanu mi bú ajunilọ

Oríkì Iṣẹ́ àárọ̀ Yorùbá: Ọdẹ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Onígbérí kíjìpá

Alákò à ń kàdá bọ̀

Anílàsà láàrin ìbọn

Alájá tí í lagogo kagbó

Ikú tí í pàmọ̀tẹ́kun

Ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ fún kìnnìhún

Eléṣù lẹ́yìn erin

Ìdágìrì àwọn ìmàdò

Olójú-iná à á sìnkú àgbọ̀nrín

Abàtàn íṣorọ́rí ẹfọ̀n


Àwọn oríkì orúkọ àmútọ̀runwá: Ìbejì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Táyélolú, Kẹ́yìndé

Ẹélà Ọba ọmọ

Gbàbílà a-rinkinkin-lọ́ṣọ̀ọ́

Olúwaà mi

Góńgó lórí ìgbágó

Tì-ẹ̀mì lórí ìyeyè

Ò-gbórí-ìyeyè nawọ́ sáboyún

Àlubọ́sà ẹgàn, agẹmọ eréwé

A-jí-folú-kẹ́


Olátúnjí Ọ̀pádọ̀tun (2001) Ewì Fún Àwọn Ògo Wẹẹrẹ Ìwé Kejì Rasmed Publications LTD. Ibadan, oju-iwe 1-12.

Olatunji Opadotun