Igi Agía
Ìrísí
Igi Méèlegbàgbé Agía tàbí Igi Méèlegbàgbé Agíya jẹ́ igi kan tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun tí kọ́kọ́ wàásù Ìyìnrere ni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lábẹ́ rẹ̀ ní ìlú Àgbádárìgì lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1842. Àgbádárìgì jẹ́ ìlú Ògù ní Ìpínlẹ̀ Èkó, orúkọ tí wọ́n sìn ń pe Igi Agía lédè Ògù ní Àsísọẹ Tín. Igi yìí gúnwà sí ẹ̀bá Ilé-ìlú Àgbádárìgì (Badagry Townhall).[1]
Pàtàkì Igi Agía
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Pàtàkì igi yìí ni wípé, lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn Òyìnbó Ajíyìnrere Thomas Birch Freeman àti Henry Townsend tí kọ́kọ́ wàásù Ìyìnrere lọ́jọ́ lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsàn-án ọdún 1842,[2][3] igi yìí wá ní ibùdó rẹ̀ fún odidi ọ̀ọ́dúnrún ọdún kí ìjì ńlá kan tó wó o lulẹ̀ ní ogúnjọ́ oṣù kẹfà ọdún 1959t.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Oluwadahunsi, Olawale (25 March 2015). "Badagry... -Footprints of slavery". National Mirror. http://www.nationalmirroronline.net/new/badagry-footprints-of-slavery/. Retrieved 18 January 2016.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ L. C. Dioka (2000). An Unsung Hero of the Church and Society: A Biography of Dominic Ogbonna Dioka. L.C. Dioka. https://books.google.com/books?id=C1yNAAAAMAAJ.
- ↑ Ige, Betty (10 June 2014). "Badagry: Recapturing lost history". The Herald News. http://www.theheraldnews.info/badagry-recapturing-lost-history. Retrieved 18 January 2016.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Toyin Falola (1999). Yoruba Gurus: Indigenous Production of Knowledge in Africa. Africa World Press. pp. 220–. ISBN 978-0-86543-699-2. https://books.google.com/books?id=aO8a3aqA0VkC&pg=PA220.