Ijapa ati adaba
Ààló oooooo
Ààlọ
Ààló yìí dá lórí Ìjàpá àti ẹyẹ Àdàbà[1]
Gẹ́gẹ́ bí a se mọ pé alágàbàgebè ni Ìjàpá, olè àti ọkànjúwà ni pẹ̀lú. Ní ayé àtijó, Ìjàpá àti àdàbà jọ ń se ọ̀rẹ́. Àdàbà ní ẹṣin kan tó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní ǹkankan. Ìjàpá ronú lọ́jọ́ kan, ó sì gbèrò bí yóó ti se pa ẹṣin Àdàbà. Ó rí pé Àdàbà gbayì láàrin àwùjọ èyí tí kò dùn mọ́ Ìjàpá nínú. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan Ìjàpá dá ọgbọ́n àlùmọkóróyí, ó pa ẹṣin Àdàbà. Àdàbà kò kúkú bínú síi kíkú tí ẹṣin rẹ kú. Ohun tí ó se ni pé ó gé ori ẹṣin náà ó bòó mọ́lẹ̀, o wá fi ojú ẹṣin síta ki ènìyàn le máa rí í dáadáa. Bí Ìjàpá tí ń lọ lo ń rí ojú ẹṣin tó yo síta . Eléyìí yàá lẹ́nu, kíá ó gbéra ó di ilé oba, nígbà tí ó dé ààfin, ó sọ fun ọba pé òun ti rí ibi ti ilè gbé lójú. Eléyìí ya ọba lénu, ó sì tún bi Ìjàpá léèrè bóyá ohun tí ó sọ dáa lójú[2]. Ìjàpá ní ó dá òun lójú, ó sì tún fi dá ọba lójú wípé kí ọba yan àwọn ẹmẹ̀wà rẹ pé kí àwọn lọ wò ibi tí ilè gbé lójú. Ìjàpá ló síwájú tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní i korin báyìí pé;
Orin Ààlọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjàpá ------------------------Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin--------------------------Ilẹ̀
Ìjàpá ----------------------------Moti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin -------------------------Ilẹ̀
Báyìí ni gbogbo wọn ń dà rẹìrẹì lo sí ibi tí ilè gbé lójú. Bí Àdàbà se gbó ohun tí Ìjàpá se yìí ni ó sáré lọ si ibi tí o bo orí ẹṣin rẹ sí tí ò sì wu kúrò nibẹ lọ sí ibòmíràn kí àwọn ẹmẹ̀wà ọba tó dé ibè[3]. Nígbà tí ọba, ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ dé ibi tí Ìjàpá wí, wọn kò rí nǹkankan, ni Ìjàpá bá bẹ̀rẹ̀ sí tú ilẹ̀ kiri títí kòri ojú kankan, ìgbà yìí ni ọba bínú gidigidi pé Ìjàpá pa irú irọ tí ó tó báyìí àti pé ó tún da òun láàmú láti wá wò ohun tí kò si níbè. Kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọn o ti ojú Ìjàpá yọ idà, kí wọn sì ti ẹyìn kìí bo akọ. Eléyìí jásí pé wọn paá. Báyìí ni ijapa fi ìlara pa ara rẹ .[4]
Ẹ̀kọ́ Ààlọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààlọ́ yìí kó wa pé kí á ma maa se ìlara ọmọlàkejì, ká jẹ kí ohun tí a bá ní tẹ wa lọ́run
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ https://www.scribd.com/book/325976572/Yoruba-Folk-Tales
- ↑ https://ng.loozap.com/ads/akojopo-alo-ijapa-apa-kini/19079098.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-05-02. Retrieved 2023-05-02.
- ↑ https://yorubafolktales.wordpress.com/