Ilé-Ìkàwé orílẹ̀ èdè Gambia

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ilé ìkàwé orílẹ̀ èdè Gambia jẹ́ ilé ìkàwé àgbà ti orílẹ̀ èdè Gambia, ó wà ní Banjul, olú Ìpínlẹ̀ Gambia.[1] Ilé ìkàwé náà wá lábẹ́ ìjọba British títí di ọdún 1946 wọ́n sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí National Library of The Gambia ní ọdún 1971. Ó wà ní abé ìdarí Gambia National Library Services Authority (GNLSA). Àkọsílẹ̀ ọdún 2016 fi hàn pé ilé ìkàwé náà ní tó ìwé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàta lé ní ọ̀kẹ́ màrún àbọ̀ (115,500). Ó sì ní òṣìṣẹ́ tí ó lé ní méjìlélógójì.

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé ìkàwé náà wà lábẹ́ ìdarí orílẹ̀ èdè British títí di ọdún 1946. Sally Njie di adarí àgbà ilé ìkàwé náà ní ọdún 1963.[2] Ìjọba British fún Gambia ní owó tí ó £575,000 fún àtúnṣe àti ìtọ́jú ilé ìkàwé náà ní ọdún 1974. Wọ́n kọ́ ilé ìkàwé míràn wọ́n sì kó àwọn ìwé lọ ibẹ̀ ní ọdún 1976.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. List of Addresses of the Major Libraries in Africa (Archived 30 June 2012 at the Wayback Machine.)
  2. Mary A. Thornhill, Factors in library development in The Gambia, Master's Thesis, Loughborough University, 1983, p.80, 89, 131.