Ilé Alájà Àkọ́kọ́ Lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ìrísí
Ilé Alájà Àkọ́kọ́ Lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni wọ́n kọ́ sí ìlú Àgbádárìgì tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Badagry lọ́dún 1845. Ìtàn sọ wípé ọdún 1842 ni àwọn òyìnbó tí wọ́n kọ́kọ́ gbé ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ tí a mọ̀ sí ẹ̀sìn kírísítẹ́nì wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ ilé alájà náà tí wọ́n sìn parí rẹ̀ lọ́dún 1845. Bíṣọ́ọ̀bù àkọ́kọ́ nílẹ̀ adúláwọ̀ Áfíríkà, Bíṣọ́ọ̀bù Samuel Àjàyí Crowther, ẹni tí ó ṣe ògbufọ̀ Bíbélì Mímọ́ láti èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá wà lára àwọn tí wọ́n ti fìgbà kan gbé inú ilé alájà àkọ́kọ́ yìí. Nínú ilé yìí ló ti ṣe ògbufọ̀ náà. [1] [2] [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Odunayo, Adams (2015-08-23). "SEE Photos Of First Storey Building In Nigeria, It Was Built 170 Years Ago". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2019-11-30.
- ↑ "First Storey Building in Nigeria Lagos State :: Nigeria Information & Guide". Nigeria. Retrieved 2019-11-30.
- ↑ "Nigeria’s first storey building records 13,609 visitors". Premium Times Nigeria. 2019-01-16. Retrieved 2019-11-30.