Jump to content

Ile-ẹjọ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
A trial at the Old Bailey in London as drawn by Thomas Rowlandson and Augustus Pugin for Microcosm of London (1808–11)
The International Court of Justice

Ilé-ẹjọ́ ni ènìyàn tàbí ibìkan tí a gbé kalẹ̀ pàá pàá jùlọ ti ìjọba tí ó ní ẹ̀tọ́ àti àṣẹ láti dájọ́, tàbí pẹ̀tù sí aáwọ̀ àwọn ènìyàn tba ẹlẹgbẹ-jẹgbé kí ó sì pàṣẹ lórí ọ̀rọ̀ kan ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìlú tí ó ń ṣàkóso rẹ̀.[1] Oríṣiríṣi ilé-ẹjọ́ ni ó wà bí òfin ìlú kọ̀ọ̀kan bá ṣe fi àyè gba wọn sí. Àwọn ilé-ẹjọ́ tí ó wà lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni: Ilé-ẹjọ́ àgbà (Supreme Court), Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn (Court of Apeal), ilé-ẹjọ́ gígá ti àpapọ̀ (Fedeal High Court), ilé-ẹjọ́ gíga ti ìpínlẹ̀ (State High Court), ilé-ẹjọ́ okòwò ti àpapọ̀ (National Industrial Court), ilé-ẹjọ́ Ṣàríà (Sharia court), ilé-ẹjọ́ ìbílẹ̀ (Customery Court) ̀ati ilé-ẹjọ́ magistrate. [2]


Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "court of law". Cambridge Dictionary. 2024-10-09. Retrieved 2024-10-13. 
  2. Wangare, Jackline (2022-08-22). "Types of courts in Nigeria and their functions explained". Legit.ng - Nigeria news. Retrieved 2024-10-13.