Jump to content

Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àyọkà yìí jẹ́ ìkan nínú àwọn àyọkà nípa
ìṣèlú àti ìjọba ilẹ̀
Nàìjíríà
 

Ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí gẹ́ẹ̀sì rẹ̀ ń jẹ́ Federal Court of Appeal of Nigeria ni ó jẹ́ ilé-ẹjọ́ àárín àti alàgata láàrín àwọn ilé-ẹjọ́ kékèké àt ilé-ẹjọ́ àgbà. [1] Ilé-ẹjọ́ yí ni ó ń gbọ́ awuye-wuye tí ó ṣúyọ lẹ́yìn ìdájọ́ àwọn ilé-ẹjọ́ kékèké ìjọba àpapọ̀ tókù.[2] Iye àwọn adájọ́ ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfinàgbà fòntẹ̀lù ní ọdún 2010 jẹ́ mẹ́rìndínlógójì. Àwọn ìgbìmọ̀ (NJC) ni wọ́n sì dábàá yíyan àwọn adájọ́ náà As at 2010, there are 66 judges of the Nigerian courts of ap fún Àarẹ kí ó tó forúkọ wọn ránṣẹ́ sí ilé Ìgbìmọ̀ adòfin agbà fún ìfòntẹ̀lù.[3] Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí ó wà káakiri ẹkùn ìdìbò mẹ́fẹ̀ẹ̀fà orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Méjìlá wà ní àárín gbùngbùn gúúsù Nàìjíríà, mẹ́wá ní apá gúúsù ìlà Oòrùn aríwá ilẹ̀ Nàìjíríà, Mẹ́wá ní ìwọ̀ Oòrùn gúúsù Nàìjíríà, mẹ́wá ní apá ìlà Oòrùn Nàìjíríà, mẹ́sàn án ní apá South-East àti mọ́kànlá ní apá ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà.[4] Olú ilé-ẹjọ́ yí wà ní ìlúÀbújá. [5]

Agbékalẹ̀ ilé-ẹjọ́ náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Adarí ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni Adájọ́ àgbà tí Ààrẹ orílẹ̀-èdè bá yàn sípò náà pẹ̀lú àbá àwọn National Judicial Council, (NJC).[6] Lẹ́yìn èyí ni àwọn ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin yóò buwọ́ lu ìyànsípò wọn. Àwọn adájọ́ ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni wọ́n gbọ́dọ̀ ní àṣẹ láti ṣíṣẹ́ gẹ́gẹ́ amòfin ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, kí wọ́n sì ti pegedé sípò adájọ́ àgbà ní nkan bí ọdún mẹ́wá sí méjìlá sẹ́yìn. [7] Gẹ́gẹ́ bí òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe làá kalẹ̀, àwọn adájọ́ ilé-ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni wọ́n gbọ́dọ̀ fiṣẹ́ sílẹ̀ ní kété tí wọ́n bá ti pé ẹni àádọ́rin ọdún.

Àṣẹ ilé ẹjọ́ náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ilé-ẹjọ́ yí ni ó ní òmìnira àti àṣẹ láti ṣíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ilé-ẹjọ́ lábẹ́ òfin tí àwọn aṣòfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bá gbé kalẹ̀. A lè rí abala òfin tó ró wọn lágbára lábẹ́ ìsọ̀rí 239 nínú ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[8] Ilé-ẹjọ́ yí tún ní àṣẹ níbàámu pẹ̀lú abala òfin 240 ti òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n ṣe àgbéyẹwò rẹ̀ ní ọdún 1999 láti gbẹ́jọ́ àwọn ilé-ẹjọ́ kékèké bíi:

  • Federal high court
  • The High Court of the States
  • High Court of the Federal Capital Territory, Abuja
  • Sharia Court of Appeal
  • Customary court of Appeal
  • Court martial
  • Tribunal[9]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Powered by DMflex WebGen --- www.dmflex.com. "Appeal Court Halts NNPC's Attempt to Stop Arbitration, Articles | THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2013-08-07. Retrieved 2015-04-28.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. Powered by DMflex WebGen --- www.dmflex.com. "Appeal Court Upholds Fayose's Election, Articles | THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2015-07-02. Retrieved 2015-04-28.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. Powered by DMflex WebGen --- www.dmflex.com. "12 New Appeal Court Justices Appointed, Articles | THISDAY LIVE". thisdaylive.com. Archived from the original on 2012-11-03. Retrieved 2015-04-28.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "OpenTrial - Nigerian Federal Court of Appeal Judge Profile Grid". opentrial.org. Archived from the original on 2013-08-17. Retrieved 2015-04-28. 
  5. "Abuja (Headquarters)". courtofappeal.gov.ng. Archived from the original on 2015-04-28. Retrieved 2015-04-28.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "NJC recommends appointments of 18 Appeal Court judges, eight court heads (FULL LIST)" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-03-19. Retrieved 2022-05-24. 
  7. "How to Be a Judge in Nigeria". LawPàdí (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-11. Retrieved 2022-05-24. 
  8. "OVERVIEW OF THE JURISDICTION OF THE COURT OF APPEAL IN NIGERIA". LawCareNigeria (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2021-02-21. Retrieved 2022-05-24. 
  9. "Jurisdiction, rights of appeal and procedure of Court of Appeal". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2020-03-10. Retrieved 2022-05-24. 

Àdàkọ:Law