Ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
Ìwé òfin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ìwé òfin tí ó ga jùlọ tí òfin inú rẹ̀ mú tẹrú-tọmọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[1][2] Ilẹ̀ Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ olómìnira ni ó ti ní oríṣiríṣi òfin tí wọ́n ń ṣamúlò tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó ṣe àgbékalẹ̀ òfin èyí tí a ń lò lónìí ní ọjọ́ kọkàndínlógún oṣù Karùn ún, ọdún 1999, tí ó bẹ̀rẹ̀ ìṣèjọba alágbádá ẹlẹ́kẹẹ̀rin irú rẹ̀.[3]
Agbékalẹ̀ òfin Nàìjíríà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ohun tí ó ń jẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni ètò ìṣèlú àwọn àtọ̀húnrìnwá àmúnisìn gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n fi kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n kéde òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1960. [4] Orílẹ̀-èdè yí ni ó ní oríṣiríṣi èdè abínibí tàbí èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n tó àrún-dín-ní-ojì lé lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ta tí àṣà wọn àti ìṣe wọn kò bàrà wọn mu.[5]Fúndí èyí, orísiríṣi ìlàkàkà ni orílẹ̀-èdè yí ti là kọjá láti ní òfin tó jingíri tí yóò sì r'ẹ́sẹ̀ walẹ̀ nínbi ìṣèjọba àti ààtò ìlú. Lára awọn ìlakakà yí ni onírúurú ìṣèjọba tí tó ti ń wáyé rí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà bí ìṣèjọba àwa-arawa. Ìjọba ológun, ìṣèjọba oníga mẹ́ta tí wọ́n ń pè ní federalism, ìṣèjọba àwọn aṣojú ṣòfin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ìpéjọpọ̀ àwọn àgbààgbà kan ni wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ òfin àkọ́kọ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà tí àwọn gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn ṣì ń lògbà tí ilẹ̀ Nàìjíríà ṣì wà lábẹ́ àkóso ìmúnisìn wọn. Àwọn òfin tí ó ṣarajọ di òfin nígbà náà ni Clifford Constitution of 1922, Richards Constitution of 1946, Macpherson Constitution of 1951, àti Lyttleton Constitution of 1954.[6][7][8]
Richards constitution
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọfin 1946 ni ilé ìjọba àmúnisìn gẹ̀ẹ́sì tó wà ní Westminster ní ilẹ̀ England fi òfin tuntun kan lọ́ọ́lẹ̀ fún ilẹ̀ amọ́nà wọn tí ó di Nàìjíríà lónìí.[9] Òfin ọ̀hún ni wọ́n pè ní Richards Constitution. Òfin tí aṣojú ìjọba ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì ìgbà náà Sir Arthur Richards, gbé kalẹ̀. Lóòtọ́, ó fi agbára sọ́wọ́ ìgbìmọ̀ àwọn aṣòfin tí ó yàn tìí kí wọ́n ma mójú tó ìṣèjọba láàrín ìlú. Bákan náà ni ó tún ṣe àgbékalẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ alẹ́nulọ́rọ̀ nín7 òfin kí wọ́n lè ma dáhùn àwọn ìbéèrè ọlọ́ka-ò-jòkan kí wón sì tún lè ma fún gómìnà níbi tí ó bá ti yẹ.
MacPherson constitution
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpàdé àpérò gbogbo gbò tó wáyé láàrín àwọn ọmọ ile-asofin nílú Ìbàdàn ní inú ọdún 1950 ni ó fa àgbékalẹ̀ àbádòfin tuntun fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọ́n wọ́n fi sórí MacPhaerson constitution tí ó jẹ́ gómìnà apàṣẹ nígbà náà, tí ó sì di òfin tuntun ní ọdún 1951.[10]
Òfin Pherson yí ni ó fàyè gba ìṣèjọba ẹsẹ̀-kùkú àti ìṣọkan ìjọba àárín gbùngbùn tííṣe ìjọba àpapọ̀, ó sì tún fọwọ́ sí dídá ìgbìmọ̀ àwọn mínísítà. Àwọn ìdáslẹ̀ wọ̀nyí ni ó fàyè gba ìṣèlú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ní inú ìjọba àpapọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ìjọba ẹsẹ̀-kùkú náà kò ṣàì gbòòrò si pẹ̀lú àwọn aṣojú lẹ́jùn-ò-jẹkùn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí wọ́n tó ọgbàọ́rùn un lé láàádọ́sàn án tí wọ́n ń ṣojú ẹkùn ìdìbò wọn. Ní kúkúrú, òfin MacPhaerson ṣègbè púpọ̀ fún ìjọba ẹlẹ́kùn-jẹkùn [11]
Lyttleton constitution
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Òfin Lyttleton ni wọ́n tún gbé kalẹ̀ ní ọdún 1954 léte àti fi ṣe Ayẹ̀wò sí òfin MacPhaerson ti ọdún 1951. Òfin yí ni ó fìdí ìṣèjọba láti àárín gbùngbùn (ìjọba àpapọ̀) rinlẹ̀ ṣinṣin ju ti àwọn tókù lọ. Àmúyẹ òfin yii ni ó ṣokùnfà òmìnira fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kúrò lọ́wọ́ àwọn gẹ̀ẹ́sì àmúnisìn.
1960 independence constitution
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Àwọn ìgbìmọ̀ alẹ́nulọ́rọ̀ nínú ìjọba ilẹ̀ Brítènì ni wọ́n fa òfin kan yọ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti màá fi tukọ̀ lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè náà gba òmìnira, òfin náà sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọjọ́ kínní osù Kẹwàá ọdún 1960 tí ó jẹ́ ayájọ́ ọjọ́ òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lábẹ́ òfin yii ni Queen Elizabeth II ti jẹ́ olórí ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí olóyè Nnamdi Azikiwe sì jẹ́ aṣojú àti agbẹnusọ rẹ̀ fún orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.[12]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Constitution of the Federal Republic of Nigeria 1999, as amended to 2018". constitutions.unwomen.org. Retrieved 14 April 2022.
- ↑ "14 Things Every Nigerian should know about the Constitution". LawPàdí (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 20 March 2021. Retrieved 14 April 2022.
- ↑ Elaigwu, J. Isawa (17 August 2006). "The Federal Republic of Nigeria". www.forumfed.org. Retrieved 14 April 2022.
- ↑ "Nigeria - Nigeria as a colony | Britannica". www.britannica.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 26 June 2022.
- ↑ Eyene Okpanachi, Eyene and Garba, Ali. Federalism and constitutional change in Nigeria, 7(1) Federal Governance 3 (2010). Archived from the original on 14 August 2020. Retrieved 28 March 2022.
- ↑ Nigeria (Constitution) Order in Council, 1954, Statutory Instrument 1954 No. 1146 (1954). Archived from the original on 30 March 2022. Accessed 30 March 2022.
- ↑ Suberu, Rotimi (2019). "Nigeria's Permanent Constitutional Transition: Military Rule, Civilian Instability and "True Federalism" in a Deeply Divided Society" (in English). Occasional Papers Series (Forum of Federations): 3–4. ISSN 1922-558X. https://constitutionnet.org/sites/default/files/2019-06/Nigeria_35.pdf.
- ↑ Nigeria (Legislative Council) Order in Council, The London Gazette No. 32838, p. 4505 (29 June 1922). Archived from the original on 21 December 2021. Retrieved 31 March 2022.
- ↑ J.O, Irukwu (19 July 2014) (in en). Nigeria at 100: What Next?. Safari Books Ltd.. ISBN 978-978-8431-44-2. https://books.google.com/books?id=_yROBAAAQBAJ&pg=PA12.
- ↑ "Nigeria - EMERGENCE OF NIGERIAN NATIONALISM". countrystudies.us. Retrieved 2023-06-07.
- ↑ "The MacPherson Constitution of 1951". Afe Babalola University ePortal. https://portal.abuad.edu.ng/Assignments/1586780885touls_paper_2.docx.
- ↑ Azikiwe, Nnamdi (12 May 2016). "From Nnamdi Azikiwe". The Martin Luther King, Jr., Research and Education Institute (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 4 July 2022.