Ile ọnọ Kanta
Kanta Mùsíọ́mù wà ní argungu ni ilú Nàìjíríà, tí ó kọ̀ ojú sì gbàgede ojú ọjà gangan
Ni ọdún 1831 ni a kọ́ kanta Mùsíọ́mù, wọ́n fún ilé náà ní orúkọ lẹ́hìn Muhammed kanta láti lè máa ṣe ìrántí fún - un, ọkùnrin yìí náà bákannáà ni ó dá ìjọba Kebbi sílè ní ọdún 1515. Yakubu Nabame, ní ó fi ilé náà lé lẹ̀, ó jé ọ̀kan lára àwọn Emir tí ó ti jẹ sẹ́yìn ni ọdún 1942 nígbàtí àwọn Gẹ̀ẹ́sì kọ́ ile-iṣẹ ìṣàkóso titun ní àkókò ìjọba Muhammed Sani . Lẹ́hìn tí ilé náà ti wà ní òfo , ní Oṣù Keje, ọjọ kinni, ọdún 1958, wón fi ilé náà ṣí Mùsíọ́mù tí ó fún ní ní òye àwọn ìtàn rúdurùdu tàbí ìwà ipá tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlè kebbi
Mùsíọ́mù náà pín sí ìyẹ̀wù mọ́kànlá, ó tún ní ìkójọpọ̀ àwọn ohun ìjà, tí ọ́ ní àwọn ọkọ́, idà, igi, àwọn òkúta, ọfà , àwọn ìbọn ìbílè pẹ̀lú àwọn ìlú tí wón fi ṣe ìfihàn sínú ilé náà .