Ilerioluwa Oladimeji Aloba (Mohbad)
Ilerioluwa Oladimeji Aloba tí ìnagijẹ rẹ̀ ńjẹ́ Mohbad tàbí Ìmọ́lẹ̀ ( wọ́n bíi ní 3 oṣù kìn-ín-ní (Ṣẹẹrẹ), ọdún 1996, ó dágbére fáyé ní 12 oṣù Kẹsán (Ọ̀wẹ́rẹ́), ọdún 2023), ó jẹ́ akọrin tàkasufe ati aṣàpílẹ̀kọ́-orin, ó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Èkó. ó kọ́ n gbé orin síta pẹ̀lu àtìlẹ́hin ilé iṣẹ́ ìgbórin síta ti Naira Marley (Marlian Records), ó kúrò ní abẹ́ ilé iṣẹ́ yí ní ọdún 2022. ó gbajúmọ̀ pẹ̀lú àwọn orin àdákọ rẹ̀ bíi "Ponmo", "Feel Good" àti "KPK (Ko Pọ kẹ) tí ó gba àmì ẹ̀yẹ àwọn orí lé (The Headies awards) ni ọdún 2022.
Wọ́n bí Ìléríolúwa Oládiméjì Alọ́ba ní Ketu,Ìpínlẹ̀ Èko, Nigeria.
Isẹ́ orin
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Mohbad gbé àwo orin àkọ́kọ́ rẹ̀ tí ó pe àkọlé rẹ̀ ni "Light" (Ìmọ́lẹ̀),jade nínú ọdun 2020, eleyi ni o tẹ̀le orin "Ponmo", tí ó ti ṣe papọ̀ pẹ̀lu Naira Marley àti Lil Kesh. Mohbad gba itọkasi ẹmarun fún àmì ẹ̀yẹ (The Beatz Awards) ní ọdún 2021.
wọ́ ka Mohbad kún àwọn olorin mọkanlelogun akọ́kọ́ (top 21) lori àtẹ Audiomack ní ọdun 2021. Ni ọdún 2022, Mohbad tún ṣe orin tuntun míràn láti ọwọ Rexxie tí ó pè ni "peace". Ó leke tente tabili aadota (50) orin TurnTable charts ní ọdún 2021 àti ọgọrun (100) àkọ́kọ́ ni ọdún 2022. Orin "peace kanna tún gbégba oróke lórí atẹ Apple Music Chart Nigeria.
Mohbad darapọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ orin "Marlian Records World" ni ọdún 2019 níbi ti ó ti gbé orin "light" jade orin yí jẹ́ ipele mẹ́jọ, Davido, Naira Marley ati Lilkesh kópa pẹ̀lu rẹ̀.
Naira Marley ni alakoso àwo orin naa pẹ̀lu àjọsepọ ilé iṣẹ́ "SB, Rexxie, P.Beat ati Austin Sinister.
Àwo orin "Blessed" ní ó kọ́ ṣe ní June 2023, lẹ́hin tí o kúro lábẹ ilé iṣẹ́ Marlian Records tí o ṣẹda ilé iṣẹ́ orin tirẹ̀ tí ó pè ni "Imolenization". Blessed jẹ́ àkójọpọ̀ orin ọtọtọ mẹjó tí wọ́n gba ogun-isẹju lapapo. lara wọn ni o ti kopa pẹlu Zlatan àti Bella Shmurda, labẹ ìsàkóso Niphkeys ati Timi Jay. Àwo naa gbégbá orókè lori àtẹ Apple Music ni Nigeria ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí o jade, àti ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí Mohbad jade laye.
Kọ́nu-kọ́họ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]NDLEA fi òfin gbe Mohbad
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní Februari 2022, àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) fi òfin gbé Mohbad, Zinoleesky àti àwọn mẹ́rin míràn ní ilé wọn tí o wà ní Lekki, ìpínlẹ̀ Èko fún níní egbò igi oloro bíi MDMA àti igbó (cannabis) ni'kawọ.
Àwọn fọọnran kan lórí ẹ̀ro ayélujara ṣe àfihàn bí àwọn òṣiṣẹ àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) ṣe wọ inú ilé àwọn olorin naa tí ó wà ní agbègbè Lekki ní ìpinlẹ̀ Eko. Gẹ́gẹ́bí wọn ṣe sọ, àwọn òṣiṣẹ àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) fi ofin mú àwọn olorin naa lai ní ìwé asẹ ifofin múni tí wón si fi ìyà tí ó lówúra jẹwọ́n.
Àjọ tí o gbógun ti lílo egbogi olóró (NDLEA) jẹri si ìréde na lati ẹnu agbẹnusọ wọn wipe lootọ ni wọn ba egbò igi oloro bíi MDMA àti igbó (cannabis) ni'kawọ wọn. Léhin-o-rẹhin wọn da Mohbad, Zinoleesky àti awọn mẹ́rin yooku sílẹ̀.
Gbódó-n-róṣọ laarin Mohbad, Naira Marley àti Sammy Larry
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Léyìn tí Mohbad ti lo ọdun meji pẹlu ilé iṣẹ́ Marlian Records ni ó kéde iyapa ati yíyan alakoso tuntun fun isẹ́ orin re. Ní ọjọ́ karun (5) October 2022, Mohbad fi ẹ̀sùn kan Naira Marley (òga rẹ nigbakan) pe oun dúnkokò mọ́ òun o si n ran àwọn kan láti maa na oun káàkiri.
Lẹ́yìn iku Mohbad ni ó hàn síta wipe saaju ni o ti kọwe sí àjọ ọlọpa ni June 2023, nínú èyí tí ó ti fi ẹ̀sùn kan Samson Erinfolami Balogun (Sam Larry) ọrẹ Naira Marley, tí o jé olu-gbe-orin larugẹ wípé o fi ìyà jẹ òun l'ónà àìtọ́ ó si tún ba dúkìá òun jẹ́. O tún tẹ̀síwájú nínú iwé náà wipe Sam Larry ko àwọn ọkunrin marundogun lẹyin wa pẹ̀lu àwọn ohun ìjà bi ibọn àti àdá ní ọwọ wọ́n wá sí ibi tí oun ti n ṣe iyaworan orin tí wọn si wípé wọn ṣiṣẹ fún Oba Elegushi. Àjọ Ọlọpa sọ wípé Mohbad ko pada yọjú sí àgọ́ wón lẹyìn tí wọn fí iwe pe lati wa fun ijiroro lori iwe ẹsun tí o kọ, àti wípé Sam Larry àti àwọn míràn tí ó fi ẹsùn kan ti kọ ìwé ìbanilórúkọjẹ́.
Ọba Ẹlẹgushi ṣe atẹjade lòdì sí ìbásepọ́ pẹ̀lu Samson Erinfolami Balogun (Sam Larry), o sì ránṣẹ́ ìbánikẹ́dun nípa iku Ilerioluwa Oladimeji Alọba (Mohbad).
Mohbad ni ọmọkunrin kan pẹ̀lu aya rẹ Omowunmi, tí wọ́n bi ni April 2023. Mohbad kú lẹ́yìn tí o lọ gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn ni 12 September, 2023 ní ọmọ ọdún mẹtadinlọgbọn (27). Àjọ ọlọpa kéde láti ṣe iwadi irú ikú tí o pa olorin naa lẹ́yìn tí wọ́n wu oku rẹ sita ni 21 September, 2023.
Ni ojo 21 Oou Kosan, odun 2023, Niran Adedokun kowe ninu Iwe iroyin Punch pe Mohbad "jo abinibi pupo ati ni ibamu polu omi orin gan-an".[1]
Nigba oniwaasu Naijiria ati buloogi ti o da ni Warri, Isaiah Ogedegbe, ti o apejuwe ro Mohbad bi "okan ninu awon akorin nla julo ni gbogbo agbaye".[2][3][4]
[5]
Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Adedokun, Niran (21 September 2023). "Nigeria failed Mohbad". Punch Newspapers. Archived from the original on 23 September 2023. Retrieved 1 October 2023.
- ↑ "Mohbad: The Story of Ilerioluwa Oladimeji Aloba -By Isaiah Ogedegbe". Opinion Nigeria. Archived from the original on 2023-09-24. Retrieved 2023-10-01.
- ↑ "The Story of Ilerioluwa Oladimeji Aloba -By Isaiah Ogedegbe". Fire News Today. Archived from the original on 2023-09-25. Retrieved 2023-10-01.
- ↑ "Mohbad: The Story of Ilerioluwa Oladimeji Aloba -By Isaiah Ogedegbe". NG Gossips. Archived from the original on 2023-09-25. Retrieved 2023-10-01.
- ↑ "Mohbad: The Story of Ilerioluwa Oladimeji Aloba -By Isaiah Ogedegbe". Nigerian Times. 24 September 2023. Archived from the original on 4 November 2023. Retrieved 11 November 2023.