Jump to content

Ipa àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 lórí ilé-iṣẹ́ oúnjẹ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àjàkálẹ̀-àrùn COVID-19 ti ní ipá lórí ile-iṣẹ ounje kari aye bi awọn ijọba orilẹ-ede ṣe gbe awọn ile-ounjẹ ati awọn ile igbafẹ tì lati lè di ìtànkálẹ̀ kokoro naa. Jakejado agbaye, awọn ero to n wọ ile-ounjẹ lojoojumọ ti dinku jọjọ ti a ba fi we iru akoko yii ni ọdun 2019. Títìpa ti wọ́n ti àwọn ile-ounjẹ pa ti ṣe akoba fun awọn ile-iṣe miran bii ipese ounjẹ, ile-ipọn'ti loriṣiriṣi ati oko'wo ọkọ ojú omi tó nkó àwọn oja kaakiri, oun pẹlu iṣẹ ọgbin. [1]

Awọn ohun ti o jẹ yọ lati ara àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ti da rudurudu silẹ ni awon agbegbe ti wọn ti n ko ounjẹ wọle pẹlu eto lójú-ẹsẹ̀.

Ni Oṣu Kẹfa ọdun 2020, Àjọ awọn orilẹ-ede Agbaaye (United Nations) kìlọ̀ pé gbogbo ayé ń dojúkọ ìdààmú oúnjẹ ti o burú jùlọ lati bii idaji ọgọrun ọdun seyin nitori ipadasẹhin oko'wo ti àjàkálẹ̀-arun naa ti fa . [2]

Àwọn pẹpẹ oúnjẹ tí ó ṣófo nítorí ọjá rira pẹ̀lú ìjayà ni Paarl, South Africa

Amòye kan lori ààbò oúnjẹ lagbaaye, Peter Alexander lati ile-ẹkọ giga ti Yunifasiti ti Edinburgh sọ wípé ọja-gbogbogboo, eto lójú-ẹsẹ̀ ti o wọpọ laarin awọn agbègbè ti o ní oko'wo ti o f'ẹsẹ mulẹ ni agbara lati bojuto awọn idalọwọduro ti o ba jẹyọ lojukannaa tabi ọwon ohun kan sugbon o ṣeeṣe ki gbogbo eto daru nitori ko si alafo ninu eto tẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ si ni ko si àkópamó kankan ti won le tọwọ bọ. [1]

Ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ni àwọn ènìyàn ti fi ìbẹ̀rù-bojo ra nkan, eleyi ti o yọrí sí ọ̀wón gógó. Àwọn ètò ìpèsè púpọ̀ ni o dojúrú; fún àpẹrẹ, awọn ìgò ti a fi n rọ èròjà tó ń mú ọwọ́ mó ti a n rà lati orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ati China ni o di ọwon gogo. Fun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ounjẹ ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bi awọn onibara ti n ra naa ni omiran n pada sori pẹpẹ, ṣugbon ibẹrubojo ti awọn eniyan fi ra ounjẹ nitori àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 ti mu ki awọn pẹpẹ ounjẹ ṣofo ti ọwon gogo si wa. Awọn ẹgbẹ kan ni orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti gba awọn ti o n ta ounje ni orílẹ̀-èdè naa ni imoran wipe ki won o maa ko ounjẹ sori pẹpẹ díẹ̀díẹ̀ lati le kapa ọwon gogo. Awọn olóúnjẹ wa lara awọn ti yoo fara gba pupọ julọ ni akoko àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 yii, ṣugbon bakannan ni won tun le ri anfani julọ ni akoko yii kanna gẹgẹbi ile-iṣẹ mohunmaworan Cheddar ti sọọ, paapaa ni lọọlọ yii. Ọpọ̀lọpọ̀ agbegbe ni iye ti wọn n ra ounjẹ yoo yatọ jọjọ.

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Jump up to: 1.0 1.1 "How are food supply networks coping with coronavirus?" (in en-GB). https://www.bbc.com/news/business-52020648. 
  2. Harvey, Fiona (9 June 2020). "World faces worst food crisis for at least 50 years, UN warns". The Guardian. https://www.theguardian.com/society/2020/jun/09/world-faces-worst-food-crisis-50-years-un-coronavirus. Retrieved 13 June 2020.