Irenije

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ìrẹ́nijẹ ni Ìgbésè fifún àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn kan ní agbára láti lè gba agbára, láti fẹ̀tọ́ àwọn mìíràn dùn wọ́n, láti lè pa àwọn mìíràn lẹ́nu mọ́ àti làti lè gàba lé àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn mìíràn. [1]Oríkì yìí fihàn pé àwọn arẹ́nijẹ ni agbára èyí tí àwọn tí wọ́n ń hùwà ìrẹ́nijẹ sí kò ní, agbára yìí ni ó sì ń fún wọn ní àǹfàní láti ṣe bí wọ́n ti fẹ́ lórí àwọn tí wọn kò ní. Ohun kóhun tí ó bá ti lè mú ẹ̀dùn ọkàn bá ènìyàn kan láti ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn, pàápàá tí kò bá kí ń ṣe ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ dá, ìrẹ́nijẹ ni.

Àwọn tí ọ̀nà tí ìrẹ́nijẹ lè gbà wáyé[2][àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Ìrẹ́nijẹ Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́dani: irúfẹ́ ìrẹ́nijẹ yìí ni èyí tí ènìyàn kọ̀ọ̀kan kópa nínú rẹ̀ nípa lílo ọwọ́ agbára lórí ẹlòmìíràn, ṣíṣe ojúṣàájú tàbí ìfẹjọ́ṣègbè.
  • Ìrẹ́nijẹ Láàárín Ọ̀wọ̀ọ́: irúfẹ́ ìrẹ́nijẹ yìí máa wáyé láàárín ọ̀wọ̀ọ́, nígbà tí àwọn kan nínú ọ̀wọ̀ọ́ náà bá fi ara wọn sọ̀kan tí wọ́n sì ń dẹ́yẹ sí àwọ́n kan nínú ọ̀wọ̀ọ́ kan náà.
  • Ìfọgbọ́n Ẹ̀wẹ́ Hùwà Ìrẹ́nijẹ: irúfẹ́ ìrẹ́nijẹ yìí máa wáyé ní àwọn iléeṣẹ́ tàbí àjọ tí ó ní àgbékalẹ̀ ajẹmọ́-òfin. Irúfẹ́ àwọn àwọn yìí ní àbùdá ṣíṣe àǹfàní fún àwọn kan àti ṣíṣe ìrẹ́nijẹ fún àwọn mìíràn
  • Ìrẹnijẹ Ajẹmọ́-àṣà: ìrẹ́nijẹ ajẹmọ́-àṣà ni irúfẹ́ ìrẹ́nijẹ tí ó máa wáyé láti ara títẹ àṣà, ìṣe àti èdè àwọn ẹ̀yà míràn mọ́lẹ̀ tàbi bíbẹnu àtẹ́ lu àṣà àwọn ẹ̀yàn mìíràn. Bí àpẹẹrẹ  nígbà tí a bá pe èdè àbínibí ọmọ fun ní fànákúlà pé kí ó máà sọ ọ́, ìrẹ́nijẹ ajẹmọ́-àṣà ni èyí jẹ́. [3]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Definition of OPPRESSION". Merriam-Webster. 2024-01-25. Retrieved 2024-01-27. 
  2. https://inclusion.msu.edu/_assets/documents/about/Forms-of-Oppression.docx. Retrieved 2024-01-27.  Missing or empty |title= (help)
  3. "Social Identities and Systems of Oppression". National Museum of African American History and Culture. 2021-12-28. Retrieved 2024-01-27.