Jump to content

Jackie Acevedo

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jackie Acevedo
Personal information
OrúkọJackie Lynn Acevedo Rangel[1]
Ọjọ́ ìbí18 Oṣù Kínní 1987 (1987-01-18) (ọmọ ọdún 37)
Ibi ọjọ́ibíAustin, Texas, United States
Ìga5 ft 2 in (1.57 m)
Playing positionStriker
Senior career*
YearsTeamApps(Gls)
2012Oklahoma City FC (WPSL)10(12)
2013Houston Aces (WPSL)9(5)
2014Portland Thorns FC2(0)
2015Houston Aces
National team
2003United States U16
United States U17
2006Mexico U202
2013Mexico1(0)
* Senior club appearances and goals counted for the domestic league only.
† Appearances (Goals).

Jackie Lynn Acevedo Rangel (tí wọ́n bí ní 18 January 1987) jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó wá láti ìlú Mexico, àmọ́ tí wọ́n bí sí ìlú America. Gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù, ipò agbábọ́òlù ata-má-tàsé ló ń gbá.

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Acevedo sí ìlú Austin, Texas, ní United States sínú ìdílé àwọn ará Mexico, ó ní àbúrò àti ẹ̀gbọ́n márùn-ún, tí ń ṣe (Jamie Acevedo, Jenny Acevedo, Alexandria King, Victoria King, àti Chancellor King). Ilé-ìwé McNeil High School ní Austin ló lọ, ó sì gba àmì-ẹ̀yẹ ti Texas State Championship ní ọdún 2004 pẹ̀lú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù McNeil. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí University of Tennessee.[2] Acevedo gbá bọ́ọ̀lù fún University of Tennessee fún ọdún kan, ní ọdún 2008 kí ó tó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga mìíràn. Acevedo gbá bọ́ọ̀lù fún ọdún mẹ́tá, fún Southern Nazarene University ní Oklahoma. Wọ́n fún ní àmì-ẹ̀yẹ gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù tó dára jù, láti ọwọ́ Sooner Athletic Conference ní ọdún 2010 àti 2011. Ó ju bọ́ọ̀lù ọgọ́rin (80) sínú àwọ̀n, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n láàárín ọdún méta rẹ̀ ní SNU.[3]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i agbábọ́ọ̀lù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní àsìkò 2012 WPSL, Acevedo gbá bọ́ọ̀lù fún Oklahoma City FC ní Women's Premier Soccer League (WPSL). Ó farahàn nígbà mẹ́wàá, ó sì ju bọ́ọ̀lù méjìlá sínú àwọ̀n, èyí tó wà ní ipò kẹta fún ìdíje náà.[4]

Ní àsìkò 2013 WPSL, Acevedo gba káàpù mẹ́sàn-án fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Houston Aces, níbi tí ó ti ju bọ́ọ̀lù márùn-ún sáwọ̀n, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ mẹ́rin. Wọ́n dárúkọ rẹ̀ mọ́ ẹgbẹ́ All-WPSL. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Houston Aces gbé ipò kejì nínú ìdíje WPSL lọ́dún náà.[4]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Convocatoria de la Selección Femenil para enfrentar a Canadá" (in Spanish). MiSeleccion.mx. Retrieved 19 October 2017. 
  2. "Tennessee Soccer: Jackie Acevedo". Tennessee Soccer. Archived from the original on 10 August 2014. Retrieved 20 July 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  3. "Jackie Acevedo". Portland Thorns. Archived from the original on 10 April 2019. Retrieved 20 July 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. 4.0 4.1 "Jackie Acevedo". Portland Thorns. Archived from the original on 10 April 2019. Retrieved 20 July 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)