James Peace

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jèmíìsì Píìsì nínú ilé

A bí Kẹ́néẹ̀ti Jèmíìsì Píìsì ní Páísílì (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Paisley) ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́sàn-án, ọdún 1963. Ọmọ ilẹ̀ Skọ́tlándì tí ó máa ń kọ orin sílẹ̀, tí ó máa ń tẹ pianó níbi tí wọ́n bá ti ń kọrin ní ìta gban̄gba tí ó sì máa ń ya àwòrán ni.

Ìgbé ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A bí Jèmíìsì Píìsì ní Páísílí, ní ilẹ̀ Skọ́tlándì ní ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ́sàn-án, ọdún 1963. Hẹ́líńsíbọ̀ (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Helensburgh) ni ó ti lo púpọ̀ nínú ìgbà èwe rẹ̀.[1][2] Hẹ́líńsíbọ̀ yìí jẹ́ ibi tí àwọn ọ̀pòlọ̀pọ̀ ènìyàn ti máa n lo oludé. Etíkun kan ní apá ìwọ̀-oòrùn ilẹ̀ Skọ́tlándì ni ìlù yìí wà. Lára àwọn ẹbí rẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ọnà (bí àpẹẹrẹ Jọ̀ọ́nú Makihíì, èdè Gẹ̀ẹ́sì: John McGhie) ó sì tún bá Fẹlíìsì Bọ́ǹsì (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Felix Burns) tan, ẹni tí ó jẹ́ olùṣẹ̀dá orin tí ó ṣeé jó sí ní àádọta ọdún àkọ́kọ́ ní sẹ́ńtúrì ogún.[1][3] Láti-ọmọ ọdún mẹ́jọ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ síí kọ́ iṣẹ́ pianó. Nígbà tí ó di ọmọ ọdún mẹ́rìnlá ni ó ṣe eré ìta gban̄gba rẹ̀ àkọ́kọ́ níbi tí ó ti ń fi orin Síkọọti Jópìlìn (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Scott Joplin) dá àwọn ènìyàn lára yá. Ní ọdún méjì lẹ́yìn èyí, wọ́n gbà á sí Ilé-ẹ́kọ̀ gíga Ajẹmọ́ba Ilẹ̀ Sìkọ́tíláǹdì fún ìkọ́ni ní Díràmà àti Músíìkì (báyìí, wọ́n ń pe ilé-ẹ̀kọ́ yìí ní Royal Conservatoire of Scotland).[1][2][3][4] Ní ilé-ẹ̀kọ́ yìí, òun ni akẹ́kọ̀ọ́ (tí kìí ṣe pé ó ń fi iṣẹ́ síṣe mọ́ ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ) tí ó kéré jù láti-ìgbà yẹn títí di ìsisìyí. Ní ọdún 1983, ó jade ní Yunifásítì Glasgow pẹ̀lú oyè B.A., ìyẹn oyè àkọ́kọ́ nínú ìpìlẹ̀-ẹ̀dá.[4][5] Inú iṣẹ́ ìkọ́ni ní pianó ni ó ti gba oyẹ̀ yìí. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ó gba dípúlọ́mà nínú músíìkì ṣíṣe lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣe eré Pianó Mẹ̀ǹdélisọ̀ùn àkọ́kọ́.[1] Àwọn òṣèré RSAMD ni wọ́n jọ ṣe eré yìí.[6] Léyìn ìgbà tí ó ti fi ẹ̀kọ́ kíkọ́ àìgbagbẹ̀fẹ̀ sílẹ̀ (ìyẹn nígbà tí ó ti pa ti a ń kàwé nílé-ẹ̀kọ́ tì), ọ̀pọ̀ ibi ní wọ́n ti máa ń fẹ̀ kí ó wá ṣeré pianó fún àwọn. Ó gbé Ẹ́dińbọ̀rọ̀ (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Edinburgh) ní ọdún 1988 títí di ọdún 1991.[1][2]

Jèmíìsì Píìsì ń gbé ní Báàdì Náòhàíìmù (Èdè Jẹ́mánì: Bad Nauheim), ní ilẹ̀ Jẹ́mánì (Èdè Jẹ́mánì: Bundesrepublik Deutschland) láti-ọdún 1991 títí di ọdún 2009.[6][7][8] Ní ọdún 1998, ọ́ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa táńgò ó sì ṣe Tango escocés (Táńgò àwọn ará ilẹ̀ Skọ́tlandì).[8][9] Ìmísí ìfi pianó ṣeré táńgò ni ó darí rẹ̀ láti-ṣeré yìí. Ní ọdún 2002, ó di ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Múísìkì ti ìlú Fikitóríà.[3][8] Ní ọdún kan náà, ó gbé eré àdánìkan ṣe lọ sí àríwá ilẹ̀ Jẹ́mánì[10] ní oṣù kẹ́sàn-án/oṣù kẹ́wàá ọdún náà ó sì lọ sí òpin gbùngbùn ìlà oòrùn ní oṣù kọkànlá ọdún kan náà níbi tí ó ti ṣeré ‘Táńgò ketàdínlógún’’ ní Họ́ng Kọngì.[8][9][10][11][12]

Ní àwọn ọdún tó tẹ̀lé èyí, ilẹ̀ Úróòpù ni ó wá dojú eré rẹ̀ kọ láìronú nípa ibòmíràn mọ́ ní sáà yìí. Ó ti ṣeré ní àwọn olú-ìlú wọ̀nyí: Amsterdam, Áténì,[13] Berlin,[14] Brussels, Hẹlisíńkì,[15] Lisbon,[16] Lọ́ńdọ̀nù, Madrid,[17] Oslo,[18] Reykjavík[19] àti Fìẹ́nnà.[20]

Ní ọdún 2008, ó di ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́lẹ́ẹ̀jì Músíìkì ti ìlú Lọndọnu fún ìmọ̀rírì àwọn ohun tó ti gbé ṣe fún táńgò.[1]

James Peace - Idylls Op.4b


Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti lo àkókò díẹ̀ ní Ẹ́díńbọ̀rọ̀[3] ó padà sí ilẹ̀ Jámìnì ní oṣù kejì ọdún 2010 ó sì ń gbé ní Wiesbaden.[1][3] Eléyìí tún jẹ́ kí èrò láti-ṣe nǹkan tuntun sọ sí i lọ́kàn ó sì ṣe fíìmù àwọn kan lára orin rẹ̀. Fíìmù tí ó ń fi ìdì òdodo mulẹ, ìyẹn “K. Jèmíìsì Píìsì ní Wiẹsìbadín”, jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn eré wọ̀nyí.[21][22]



Àwọn Oyè tí a Gbà fún Ẹ̀kọ́ tí a Kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

●    Ipò Kìíní, Ìdíje Aginẹẹsi Mílà (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Agnes Millar Prize for sight-reading). Glasgow, ọdún 1983[4]

Tango XVIII by James Peace (James Peace, piano)

●    Ipò Kìíní, Ìdíje Dúníbàrìtọ́nìshíìrì EIS (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Educational Institute of Scotland Prize for piano accompaniment). Glasgow, ọdún 1984[4]

●    Ẹ̀bùn níbi àròkọ Sìbẹ́líọ̀sì, Glasgow, ọdún 1985[4]

●    Dípúlọ́mà tí a fi dá ni lọ́lá, Ìdíje Gbogbogbòò Àròkọ TIM (Èdè Ítálì: Torneo Internazionale di Musica). Rómù, ọdún 2000[1][2][5]

Tango Milonga op. 26

●    Dípúlọ́mà tí a fi dá ni lọ́lá ti IBLA Foundation. New York, ọdún 2000[1][2][5]

●    Mẹ́dà ìràntí ti Ẹgbẹ́ Abèjì ti Pianó Àgbáyé. Tokyo, ọdún 2002[1][2][5][23]

●    Mẹ́dà Góòlù ti International Academy ti “Lutèce”. Parisi, ọdún 2005[1][2]

Àwọn Músíìkì tí ó Ṣe Kókó tí ó Jẹ́ Àkọsílẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

•Omi tí ó ń ti ibi gígà sàn wálẹ̀ (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: The Waterfall)[24]

•Àwọn Ìdìílì (Èdè Gẹ̀ẹ́sì Idylls)

•Orin òwúrọ̀ àrọrakọ (Èdè Faransé: Aubade)

•Omi ojú tí kò máriwo dání (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Silent Tears)

•Ewé tí a ti gbàgbé (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Forgotten Leaves)

•Bàlàádì (Èdè Faransé: Ballade)

•Àṣeyẹ fún ìránti nọńba 1 (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Ceremonial March No.1)

•Àṣeyẹ fún ìránti nọńba 2 (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Ceremonial March No.2)

•Góòlù ti Ọtọ́ọ̀mù (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Autumn Gold)[25]

•Orin ayérayé (Èdè Gẹ̀ẹ́sì: Eternal Song)[1]

•“Fún Jọ́jíà” (Èdè Jọ́jíà: საქართველოსთვის)                                                           (Ohun tí a kọ sílẹ̀ fún kíkọ: Tamari Chikvaidze, Zurabi Chikvaidze àti James Peace)

•Táńgò mẹ́rìnlélógún fún àdáfi-piano kọ[1][9][21][22]

Ìbáṣepọ̀ tí ó bá àwọn ará ìta ní[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Souvenir de Buenos Aires (fún àdáfi-piano) - YouTube

Autumn Gold - YouTube

Lento Lacrimoso - YouTube

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 Birgitta Lampert. “Láìsí àwọn ohùn tó máa ń bíni nínú”. Wiesbadener Tagblatt (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọjọ́ kẹ̀wá, oṣù kejì, ọdún 2011       
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 2.5 2.6 Julia Anderton. “Táńgò tó dàbí ìtàn adùn-tó-korò”. Wiesbadener Kurier (Magasín-ìn-nì Jámìnì), ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù kẹta, ọdún 2012
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 3.4 Sabine Klein. “Orin mi dàbá èmi fúnraàmi” - ó níí ṣe pẹ̀lú ìfẹ́”. Frankfurter Rundschau (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọdún 1992 (ìtẹ̀jáde 254), ojú-ìwé 2
  4. 4.0 4.1 4.2 4.3 4.4 G. Müller. “Ẹ̀mí pianó ń jó táńgò”. Kulturspiegel Wetterau (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọjọ́ kẹtàndínlógún, oṣù karùn-ún, ọdún 2001, ojú-ìwé 5               
  5. 5.0 5.1 5.2 5.3 Deutsche Nationalbibliothek. “James Peace”
  6. 6.0 6.1 “James Peace”. FRIZZ (Magasín-ìn-ní Jámìnì), oṣù kìíní, ọdún 2012, ojú-ìwé 5
  7. Manfred Merz. “Ilé aláwọ́ tí ó rọ̀ mọ́ ìfẹ́ tí ó mú mímọ̀-ọ́nṣe dání tí ó sì wọni lára”. Wetterauer Zeitung (Magasín-ìn-ní Jámìnì), ọjọ́ kejìlá, oṣù kọkànlá, ọdún 1992, ojú-ìwé 19               
  8. 8.0 8.1 8.2 8.3 "James Peace”. The Tango Times (Magasín-ìn-ní Níú Yọòkì). Ní ìgbà òtútù, (ọdún) 2002-2003. ìtẹ̀jáde 39. Ojú-ìwé 1 sí 5
  9. 9.0 9.1 9.2 National Library of Scotland. “Tango escocés
  10. La Cadena (Magasín-ìn-ín Dọ́ọ̀jì). Oṣù kẹ́sàn-àn, ọdún 2002, ojú-ìwé 26   
  11. Tangotang (Ìwé-àtẹ̀jáde Họ́ńgì Kọǹgì). Ọjọ́ kẹjọ, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2002
  12. “James Peace”. South China Post (Ìwé-ìròyìn Họ́ńgì Kọńgì), ọjọ́ kẹ́sàn, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2002
  13. Magasín-ìn-ní kékeré tí ètò orin kíkọ ìta gban̄gba wà nínú rẹ̀ (Àtẹ́ẹ̀nì). {Για σένα, Αγγελικη}. Ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹ̀wàá, ọdún 2016
  14. Tangodanza (Magasín-ìn-ní Jámìnì). Oṣù kìíní, ọdún 2002 (9)
  15. Ìwé-ìkéde ètò orin kíkọ ìta gban̄gba (ìrìnàjò afẹ́ orin kíkọ ìta gban̄gba Fínlándì, ọdún 2014)
  16. Ìwé-ìkéde ètò orin kíkọ ìta gban̄gba (ìrìnàjò afẹ́ orin kíkọ ìta gban̄gba Pọ́rtúgàl, ọdún 2016)
  17. Ìwé-ìkéde ètò orin kíkọ ìta gban̄gba (ìrìnàjò afẹ́ orin kíkọ ìta gban̄gba Sípéènì). «¡Feliz cincuenta cumpleaños, 2013!».
  18. Listen.no. Konsert, James Peace (Flygel). Munch Museum (ilẹ́ ọnà). Ọjọ́ kẹrindilógún, ọsù kẹ̀wàá, ọdún 2004
  19. Ríkarður Ö. Pálsson. “Skozir Slaghörputangoár”. Morgunblaðið (Ìwé-ìròyìn Íslándí), ọjọ́ kẹrìnlá, ọsù kẹ̀wàá, ọdún 2004
  20. Magasín-ìn-ní kékeré tí ètò orin kíkọ ìta gban̄gba wà nínú rẹ̀ (Fienna). Ọjọ́ kẹtàlelógún, oṣù kìíní, ọdún 2005
  21. 21.0 21.1 National Library of Scotland. “K. James Peace in Wiesbaden”
  22. 22.0 22.1 Deutsche Nationalbibliothek. “K. James Peace in Wiesbaden”
  23. Ẹgbẹ́ Abèjì tí Pianó Àgbáyé. Ó ṣe Àkọsílẹ̀ Àwọn tí ó gba Ẹ̀bùn (Tokyo)
  24. Wiesbadener Staatstheater (magasín-ìn-ní kékeré tí ètò orin kíkọ ìta gban̄gba wà nínú rẹ̀), oṣù kẹ́sàn-àn, ọdún 2021
  25. Schwäbische Post. “Ohùn faolín-ìn-nì ga sókè réré ju ti àwọn òṣèré”. Ọjọ́ kẹrìn, oṣù kẹfà, ọdún 1994