Jill Levenberg

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jill Levenberg
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹ̀sán 20, 1977 (1977-09-20) (ọmọ ọdún 46)
Orílẹ̀-èdèSouth African
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Cape Town
Iṣẹ́Actress

Jill Levenberg (tí a bí ní 20 Oṣù Kẹẹ̀sán, Ọdún 1977) jẹ́ òṣèrébìnrin ọmọ orílẹ̀-èdè Gúùsù Áfríkà.

Ìsẹ̀mí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Levenberg gbé ní agbègbè Kensington, il̀ú Cape Town.[1] Láti ìgbà tí ó wà ní ọmọ ọdún mẹ́fà ló ti ṣe àkọ́kọ́ eré rẹ̀ lóri ìpele nígbà kan tí ó fí kọrin ní ilé-ìṣeré Kensington Civic Centre. Ó kópa nínu ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn eré, bẹ́ẹ̀ ló sì tún jẹ́ alápọn nínu ẹgbẹ́ akorin ní àkókò ilé-ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ rè. Levenberg lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga University of Cape Town níbi tí ó ti gba oyè-ẹ̀kọ́ nínu ìmọ̀ eré ìtàgé àti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Levenberg kópa nínu ọ̀pọ̀lopọ̀ àwọn eré bii Medea, Blood Brothers àti Orpheus in Africa ní ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ó gba àmì-ẹ̀ye amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ òṣèré tí ó tayọ jùlọ fún ipa rẹ̀ nínu Orpheus in Africa[2]

Levenberg kópa gẹ́gẹ́ bi Beulah nínu fíìmù ti ọdún 2015 kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Abraham. Ní ìbẹ̀rè ọdún 2015, ó ti kópa gẹ́gẹ́ bi Mymoena Samsodien nínu eré tẹlifíṣọ̀nù alátìgbà-dègbà kan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Suidooster.[2] Ní ọdún 2020, Levenberg dá àbá pé kí eré náà tún sọ̀rọ̀ lóri ìlóbìnrin púpọ̀, èyítí ó mú kí AB tí ó jẹ́ ọkọ rẹ̀ nínu eré náà fẹ́ Farah gẹ́gẹ́ bi ìyàwó ẹlẹ́kejì.[3]

Ní ọdún 2018, Levenberg kó ipa Ellen Pakkies nínu eré Ellen: The Ellen Pakkies Story, èyí tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ ipa rẹ̀ nínu sinimá àgbéléwò.

Levenberg jẹ́ olùjàfẹ́tọ̀ọ́ àwọn òṣèré tí ó sì maá n tako ṣíṣe ayédèru fíìmù.[2] Levenberg tún maá n ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀fẹ́ nípa eré yógà àti eré orí-ìtàgé fún àwọn ọ̀dọ́ ní ìlú Cape Town.[4] Ó jẹ́ elédè Gẹ̀ẹ́sì, Afrikaans, àti Jẹmánì[5]

Àṣàyàn àwọn eré rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • 2015: A Whistle Blows/Fluit-Fluit (as Gwen Isaacs)
  • 2015: While You Weren't Looking (as Yasmin)
  • 2015: Uitvlucht (as San)
  • 2015: Abraham (as Beulah)
  • 2015-present: Suidooster (TV series, as Mymoena Samsodien)
  • 2018: Ellen: The Ellen Pakkies Story (as Ellen)

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtakùn Ìjásóde[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]