Jump to content

Jimoh Aliu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jímọ̀ Àlíù
Ọjọ́ìbí(1939-11-11)11 Oṣù Kọkànlá 1939
Òké-Ìmẹ̀sí, Nigeria
Aláìsí17 September 2020(2020-09-17) (ọmọ ọdún 80)
Adó Èkìtì, Nàìjíríà
Orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Orúkọ mírànÀwòrò
Ọmọ orílẹ̀-èdèNàìjíríà
Iṣẹ́
  • Actor
  • dramatist
  • producer
Ìgbà iṣẹ́1959–2020

Jímọ̀ Àlíù, MFR (November 11, 1939 – September 17, 2020), tí a tún mọ̀ sí Àwòrò, jẹ́ agbẹ́gilére òṣèré orí-ìtàgé ati sinimá, olùkọ̀tàn àti adarí eré ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. [1]

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí alàgbà Jímọ̀ ní ọjọ́ kọkànlá oṣù Kọkànlá ọdún 1939 ní Ìlú Òké-Ìmẹ̀síÌpínlẹ̀ Èkìtì ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Bàbá rẹ̀ Àlíù Fákọ̀yà, jẹ́ baba aláwo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ìlú Òké-Ìmẹ̀sí, nígbà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí Ìlú Ìlórò-Èkìtì.[2][3]

Ìṣe rẹ̀.gẹ́gẹ́ bí òṣèré

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àlíù dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèré Akin Ògúngbè nígbà tí gbajú-gbajà òṣèré yí gbé eré ìtagé kan wá sí ìlú rẹ̀.[4] Ní ọdún 1966, ó dá ẹgbẹ́ òṣèré tirẹ̀ ìyẹn "Jímọ̀ Àlíù Concert Party" tí gbé kalẹ̀ ní ílú Ìkàrẹ́Ìpínlẹ̀ Òndó lẹ́yìn tí ó ti lo ọdún méje lẹ́yìn nínú ẹgbẹ́ Ògúngbè[5]

Àwòrò dara pọ̀ mọ́ ilé iṣẹ́ Ológun ilẹ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1967 àmọ́ ó fẹ̀yìn tì ní ọdún 1975 kí ó lè fọkàn balẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ eré orí-ìtàgé, àti láti mú ìdàgbà-sókè bá eré lábẹ́ orúkọ ilé iṣẹ́ ìgbéréjáde rẹ̀ tí ó pè ní Jímọ̀ Àlíù Cultural Group[6] Jímọ̀ ti gbé àwọn eré oríṣiríṣi Yánpọn-yánrin, Ikú Jàre Ẹ̀dá, Fọ́pomọ́yọ̀ jáde lórí ẹ̀rọ amóhù-máwòrán.[7][8]

Jímọ̀ Àlíù kú ní ọmọ ọgọ́rin ọdún ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kẹsàán ọdún 2020 sí ilé-ẹ̀kọ́ ìkọ́ṣẹ́ ìṣègùn ti Fásitì Adó-Èkìtì lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́. .[9]

Àwọn sinimá àgbéléwò rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  • Fọ́pomọ́yọ̀
  • Yánpọn-yánrin
  • Àjálù
  • Àrélù
  • Igbó Ẹlẹ́jẹ̀
  • Ìrìnkèrindò
  • Rúkèrúdò

Àwọn àmì ẹ̀yẹ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2015-02-16. Retrieved 2020-09-18. 
  2. Administrator. "MY DIVORCE WITH ORISABUNMI WAS DESTINED----Chief Jimoh Aliu a.k.a. Aworo MFR — nigeriafilms.com". nigeriafilms.com. Retrieved 16 February 2015. 
  3. "From stage to traditional medicine". The Punch — Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 16 February 2015. Retrieved 16 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Veteran actor, Ogungbe, dies at 78". The Punch — Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 16 February 2015. Retrieved 16 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "For Ogungbe, dramatists besiege Abeokuta". The Punch — Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 16 February 2015. Retrieved 16 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "Strangers to their mother tongues: Home-bred Nigerians who don’t speak their native languages". The Punch — Nigeria's Most Widely Read Newspaper. Archived from the original on 16 February 2015. Retrieved 16 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  7. "African Cinema". google.nl. Retrieved 16 February 2015. 
  8. BOLDWIN ANUGWARA. "How I lied to become music star – KSA". Newswatch Times. Archived from the original on 16 February 2015. Retrieved 16 February 2015.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  9. BREAKING: Veteran Yoruba Actor, Jimoh Aliu, Is Dead, To Be Buried On Friday