Josephine Okwuekeleke Tolefe
Captain Josephine Okwuekeleke Tolefe tí a bí ní ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1931 jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti òṣìṣẹ́bìnrin àkọ́kọ́ tí a fún láṣẹ láti jẹ́ adarí àti ọ̀gágun kejì nínú ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ ológun ilẹ̀ Nàìjíríà.[1][2]
Ìgbésí ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọjọ́ karùn-ún oṣù kejì ọdún 1931 ni a bí Josephine ní Ogwashi-Uku tó wà ní apá Gúúsù Aniocha ní ìpínlẹ̀ Delta.[3] Ó ṣe ìdánwò fún ìwé-ẹ̀rí ti University of Cambridge ní ọdún 1950. Lẹ́yìn náà ni ó lọ sí ilé-ìwé àwọn agbẹ̀bí Midwives Training College, High Coombe ní Surrey ní United Kingdom. Ó sì jáde ní ilé-ìwé náà bí Nọ́ọ̀sì tí ó forúkọ sílẹ̀ tí ó wà lábẹ́ General Nursing Council fún England àti Wales ní oṣù kẹjọ ọdún 1956. Central Midwives Board of England sì gbà á wọlé láti ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù kejìlá ọdún 1961.[4]
Iṣẹ́ tó yàn láàyò
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Josephine jẹ́ nọ́ọ̀sì akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àmọ́ ó pinnu láti dára pọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ ológun ti ilẹ̀ Nàìjíríà nítorí ìfẹ́ tó ní sì àwọn obìnrin tí ó wà lára ìgbìmọ̀ ológun ilẹ̀ Britain àti pé ó wùn ún láti jà fún orílẹ̀-èdè rẹ̀.[5]
Lẹ́yìn tí ó dara pọ̀ mọ́ ìgbìmọ̀ náà, wọ́n yàn án sípò ọ̀gágun kejì ní ọdún 1961. Lẹ́yìn ọdún méjì, wọ́n yàn án sípò adarí.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbóríyìn fún, òun àti àwọn obìnrin yòókù tí ó wà ní ìgbìmọ̀ ológun náà ń kojú ìgbèníjà lóríṣiríṣi láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin tọ́ jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀.[6] Ní ọjọ́ karùn-ún ọdún 1967, ó gba ìfẹ̀yìntì fúnra rẹ̀. Ní ọdún 2014, arábìnrin náà di olóògbé.[7]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "First Women: Josephine Okwuekeleke Tolefe Is The First Woman To Become An Army Captain In Nigeria". Woman.NG. 2018-06-21. Archived from the original on 2020-10-25. Retrieved 2020-05-02.
- ↑ "Vanguard News". Meet the first female army officer in Nigeria. 2011-12-10. Retrieved 2020-05-02.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ Osuyi, Paul (2011-12-12). "Nigeria’s first female Army Captain:I carry military discipline in my blood". Africa Defense Journal. Retrieved 2020-05-02.
- ↑ "Global Sentinel". Global Sentinel. Retrieved 2020-05-02.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Meet the first female army officer in Nigeria". Vanguard News. 2011-12-10. Retrieved 2020-05-02.
- ↑ "Gender equality in the Nigerian military – My Army". My Army – Just another WordPress site. 2017-10-29. Retrieved 2020-05-02.[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ "Nigeria's first female commissioned officer is dead.". Facebook. Retrieved 2020-05-02.