Julie Coker
Julie Coker jẹ́ akọ̀ròyìn àti akàròyìn ti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nígbà kan rí. Ó jẹ́ akàròyìn tó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Ìgbésí ayé àti ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Bàbá Coker jẹ́ ọmọ Yorùbá láti ìlú Abẹ́òkúta nígbà tí ìyá rẹ̀ wá láti ẹ̀yà itsekiri ní agbègbè Warri.[1] Ìlú Èkó ní ó dàgbà sí tí ó sì ti bẹ̀rẹ̀ ètò-ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó lọ sí St Mary's Convent primary school, èyí tí àwọn ajíhìnrere Catholic gbé kalẹ̀. Ní ilé-ìwé, ó nífẹ̀ẹ́ sí ẹgbẹ́ akọrin. Ilé-ìwé Holy Child College ni ó lọ lẹ́yìn náà. Ó kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro àmọ́ ó ní àǹfààní láti rí ètò-ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ gbà ní Holy Child College. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní Warri. Ibẹ̀ ni ó ti rí tí ó sì kópa nínú ìdíje Miss Western Nigeria Competition ní ọdún 1958 tí ó sì yege nínú ìdíje náà.[2] Ní ọdún kan náà, ó tún yege nínú ìdíje Miss Nigeria.
Iṣẹ́ rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ọdún 1959, ó dara pọ̀ mọ́ WNTV, ó ń ṣiṣẹ́ agbàlejò àmọ́ ìgbà tí Anike Agbaje-Williams lóyún tó sì fẹ́ gba ìsinmi ni wọ́n yan Coker láti rọ́pò Anike.[3] Coker wá di ọkàn lára àwọn akàròyìn tó gbajúmọ̀ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lẹ́yìn tí WNTV jẹ́ tẹlifíṣọ́ọ̀nù àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Coker jẹ́ obìnrin akàròyìn kejì níbẹ̀.
Yàtọ̀ sí iṣẹ́ akàròyìn, Coker jẹ́ akọrin àti òṣèré. Ó kópa nínú fíìmù àgbéléwò Dinner with the Devil.[4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Gabriel, Chioma (16 April 2011). "I was given out in marriage at 14 years but I ran away- Julie Coker - Vanguard News". Vanguard News. https://www.vanguardngr.com/2011/04/i-was-given-out-in-marriage-at-14-years-but-i-ran-away-julie-coker/.
- ↑ Ekunkunbor, Jemi (13 August 2017). "My journey into fame was magical — Julie Coker - Vanguard News". Vanguard News. https://www.vanguardngr.com/2017/08/journey-fame-magical-julie-coker/.
- ↑ "Nigeria: Broadcasting is Like Bathing in Public... Anike-Agbaje Williams". This Day (Lagos). 28 November 2006. Archived from the original on 16 December 2019. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ "IN MY TIME, WE KNEW NOTHING ABOUT GENOTYPE â€" JULIE COKER" (in en). Nigerian Voice. https://www.thenigerianvoice.com/news/29455/in-my-time-we-knew-nothing-about-genotype-julie-coker.html.