Kámẹ́rà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Leica kámẹ́rà (1950s)
Hasselblad 500 C/M with Zeiss lens

Kamẹ́rà jẹ́ àpótí rébété tí ó ní ojú tí a lè fi yan àwòrán yálà àwòrán onígun méjì tàbí mẹ́ta. Gbogbo àwọn kámẹ́rà ni wọ́n ma ń jẹ́ àpótí rébété kan tí a kàn pa tí ó ní ihò bíntín tí oyè ìmọ́lẹ̀ lè gbà kọjá láti gba àwòrán sílẹ̀ sínú díígí tí wọ́n ti ṣepa sínú rẹ̀.[1] Kámẹ́rà [2] ní àwọn irinṣẹ́ kan tí wọ́n ma ń lò láti fi ya àwòrán ní àsìkò tí kò bá sí inọ́lẹ̀ tó já geere. Lára rẹ̀ ni lẹ́nsì tí wọ́n sopọ̀ mọ́ àpótí kámẹ́rà náà. Lára rẹ̀ náà ni ìrìnṣẹ́ tí wọ́n ń pe ní shutter speed [3], èyí ni ó ma ń ka iye àsìkò àti eré tí mọ̀nà-mọ́ná gbà keje nínú Kámẹ́rà náà.

Àwòrán tí ó dúró bọrọgidi ni won sábà ma ń fi Kámẹ́rà yà, ba kan náà ni wọ́n ti ń fi kámẹ́rà ya àwọn àwòrán tí wọ́n ń lọ tí wọ́n bọ̀. Irúfẹ́ àwọn àwòrám tí wọ́n ń lọ bọ̀ yí a wọ́n ń ṣàkójọ rẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣe fíímù agbéléwò tàbí sinimá.

Àwọn itọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Definition of CAMERA". Merriam-Webster. 2023-05-22. Retrieved 2023-05-23. 
  2. "Photography 101: Understanding Camera Lenses Basics - 2023". MasterClass. 2019-01-25. Retrieved 2023-05-23. 
  3. Mansurov, Nasim (2018-01-17). "Understanding Shutter Speed for Beginners". Photography Life. Retrieved 2023-05-23.