Kúnlé Afod

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Kúnlé Afod tí a bí ní ọjọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kẹwàá, [1] ọdún 1973 (24-10-1973) jẹ́ òṣèré Sinimá àgbéléwò Yorùbá tí wọ́n bí ní ìpínlẹ̀ Èkó, [2] àmọ́ tí òṣẹ̀ wá láti ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí ó sì jẹ́ akọ́bí nínú ọmọ mẹ́rin tí àwọn òbí rẹ̀ bí. [3]

Ètò ẹ́kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kúnlé bẹ̀rẹ̀ ẹ́kọ́ rẹ̀ ní Ilé-ẹ́kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ní ìlú Festac ní ìpínlẹ̀ Èkó tí ó sì parí rẹ̀ ní ìlú Ọ̀wọ̀ ní ìpínlẹ̀ Òndó , kí ó tó lọ sì Ilé-ẹ́kọ́ oníwé mẹ́wá ti Command tí ó wà ní ìlú Jos.[4]

Iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ òṣèré[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà rẹ̀ lábẹ́ àwọn ọ̀gá rẹ̀ Tọmọlójù Jídé Ògúngbadé àti Jàgan Aníkúlápó , kí ó tó dara pọ̀ mọ́ ikọ̀ Àwàdà Kẹríkẹrì lábẹ́ àkóso Adébáyọ̀ Sàlámì, tí wọ́n ń pè ní Ọ̀gá Bello.

Àwọn ẹbí rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kúnlé ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Désọ́lá, tí wọ́n sì bímọ.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Kunle Afod Biography: Age & Movies". 360dopes. 2018-07-17. Retrieved 2020-01-04. 
  2. Published (2015-12-15). "I turned down romantic roles because of my wife - Kunle Afod". Punch Newspapers. Retrieved 2020-01-04. 
  3. "Kunle Afod, His Wife And Their 4 Sons In Adorable Family Photo". Within Nigeria. 2018-06-12. Retrieved 2020-01-04. 
  4. "Kunle Afod Reveals his First Child Many People Do Not Know (Photos)". Daily Family NG. 2018-12-31. Retrieved 2020-01-04.