Jump to content

Kọ́nsónántì èdè Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Kọ́ńsónáǹtì Yorùbá ni ìró kọ́ńsónáǹtì ni ìró tí a pè tí ìdíwọ́ wà fún afẹ́fẹ́ tàbi èémí nínú káà-ẹnu. Kọ́ńsónáǹtì méjìdínlógún ló wà lédè Yorùbá. Àpẹẹrẹ kọ́nsónántì èdè Yorùbá ni: b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w àti y.

Ìlò kọ́nsónántì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Nínú èdè Yorùbá, kọ́nsónántì kìí dá dúró, ba kan náà ni we kìí b parí ọrọ̀ Yorùbá. Amọ́, wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ kí wọ́n sí wà ní àárín ọrọ̀ tàbí gbólóhùn nítorí àfibọ̀ ni wọ́n ma ń fi kọ́nsónántì àti fáwẹ́lì ṣe nínú èdè Yorùbá. Àpẹẹrẹ:

  • Dòdò
  • Tafà-tafà
  • Yẹ̀rì
  • Apá
  • Bàtà ati bbl.

Òfin kọ́nsónántì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn òfin ìsàlẹ̀ yí ni ó de kọ́nsónántì èdè Yorùbá: 1. Kọ́nsónántì kìí da dúró: ofin yí sọ wípé kọ́nsóndntí kìí da dúró àyàfi kí ó fara pẹ́, rọ̀ mọ́ ìró fáwẹ́lì kí wọ́n tó lè wúlò nínú èdè Yorùbá, amọ́ ó lè da dúró nínú èdè míràn.

2. Kọ́nsónántì kìí tẹ̀lé ara wọn: èyí túnọ̀ sí wípé kọ́nsónántì méjì tàbí mẹ́ta kò lè tẹ̀lé ara wọn nínú ọrọ̀ kan ṣoṣo gegeẹ́ bí a ti ń ri nínú àwọn èdè míràn. Àpẹẹrẹ rẹ̀ ni:

  • Shittu (t & t) ❌ ayafi kí ó jẹ́
  • Ṣítù ✅

3. A gbọ́dọ̀ ṣe àfibọ̀ kọ́nsónántì àti fàyèẹ́lì: òfin túmọ̀ sí wípé bí a bá fẹ́ ṣe afọ̀ tí ó yanrantí, a ní láti ṣe àfibọ̀ kọ̀nsónántì ati fàwẹ́lì papọ̀ kí èdè wa tó lè ní ìtumọ̀ tí ó ja gaara. Àpẹẹrẹ ni:

Ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Àárín ọ̀rọ̀ Ìparí ọ̀rọ̀

b = Bàbá (father) b = Àbádà (slap) b = Ẹbẹdí

Àwọn Itọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]