Jump to content

Kafui Danku

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kafui Danku
Ọjọ́ìbí16 Oṣù Kẹjọ 1983 (1983-08-16) (ọmọ ọdún 41)
Orílẹ̀-èdèGhanaian
Ọmọ orílẹ̀-èdèGhanaian
Iléẹ̀kọ́ gígaUniversity of Cape Coast
Iṣẹ́Ghanaian Actress and movie producer
Gbajúmọ̀ fúnAlvina: Thunder and Lightning
I Do
4Play.
Àwọn ọmọ2

Kafui Danku jẹ́ òṣèrébìnrin àti aṣàgbéjáde eré, tó gbajúmọ̀ fún ìkópa rẹ̀ nínú àwọn fíìmù bíi Any Other Monday, Alvina: Thunder and Lightning, I Do, and 4Play.[1][2][3][4] Ó sì tún jé òǹkọ̀wé ìwé Silence Is Not Golden.[5]

Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé àti ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Kafui ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹjọ, ọdún 1982.[6] Ó dàgbà sí Ho, ìlú rẹ̀ sì ni Tanyigbe-Etoe, èyí tó jẹ́ ìlú kan ní agbègbè Volta ní Ghana. Ó gba ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ ní Mawuli Primary àti JSS.[7] Ó tún lọ sí Ola Girls School ní agbègbè Volta ní Ghana, tí ó sì tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní University of Cape Coast, ní ààrin gbùngùn Ghana[8], níbi tí ó ti gboyè ẹ̀kọ́ nínú ẹ̀kọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì.[9]

Kafui bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ eré ṣíṣe ní United Nations ṣáájú ìgbà tó wọ Ghana Movie Industry ní ọdún 2009.[10] Ó jẹ́ òṣèrébìnrin bẹ́è sì ni ó tún jẹ́ òǹkọ̀wé.[11] Yàtọ̀ sí èyí, ó jẹ́ alágbàwí, Vlogger àti akópa nínú ìdíje arẹwàobìnrin. Ó kópa nínú ìdíje arẹwà obìnrin, ó sì gbéga orókè gẹ́gẹ́ bíi Miss Ghana ní ọdún 2004. Òun ni olùdásílè ABC Limited (ABC Pictures GH), èyí tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń ṣe àgbéjáde fíìmù ní Ghana.[12] Fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Ghana ni Agony of the Christ, èyí tí àwọn òṣèré bí i Majid Michel àti Nadia Buari kópa nínú.[13]

Ìgbésí ayé ara ẹni

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó fẹ́ arákùnrin kan tó wá láti canada [14][15] tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kojo Pitcher.[11] Àwọn méjèèjì fẹ́ ara wọn ní ọdún 2011. Wọ́n bí ọmọ méjì, tí orúkọ wọn ń jẹ́; Lorde Ivan Pitcher àti Titan Pitcher.[16] [11] Kafui ní àbúrò méjì. Àwọn òbí rẹ̀ ni Madam Agnes Asigbey (tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó ti fẹ̀yìntì) àti Olóògbé John Danku.[17]

Ní oṣù karùn-ún ọdún 2018, ó ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò kan, èyí tí ó pè ní 'Ghana Power Kids Charity Ball' láti fi máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn ọmọdé ní ẹ̀ka Kwashiorkor ti Princess Marie Louise Children's Hospital ní Accra.[18]

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Actress Kafui Danku has given birth". www.ghanaweb.com. Retrieved 13 June 2018. 
  2. "Trailer: Kafui Danku to premiere 'Any Other Monday' on March 4". www.ghanaweb.com. Retrieved 13 June 2018. 
  3. Mawuli, David. "Kafui Danku: Actress And Producer Says, Romantic Roles In Movies Do Not Affect Her Marriage Life". Archived from the original on 10 July 2018. Retrieved 13 June 2018. 
  4. "Kafui Danku". IMDb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-12-14. 
  5. "Kafui Danku launches 'Silence Is Not Golden' book; urges women to speak out". www.ghanaweb.com. Retrieved 13 June 2018. 
  6. Plug, Ak (2020-11-24). "Kafui Danku Biography, Movies and Net Worth in 2023 - Afrokonnect" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-13. 
  7. Empty citation (help) 
  8. Mawuli, David. "Kafui Danku: Actress And Producer Says, Romantic Roles In Movies Do Not Affect Her Marriage Life". Archived from the original on 10 July 2018. Retrieved 13 June 2018. 
  9. Plug, Ak (2020-11-24). "Kafui Danku Biography, Movies and Net Worth in 2023 - Afrokonnect" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-11-13. 
  10. bigedemtimes (2022-10-28). "Kafui Danku biography". Times In Ghana (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2023-09-06. 
  11. 11.0 11.1 11.2 "Ẹda pamosi". Archived from the original on 2023-08-23. Retrieved 2024-08-22. 
  12. Empty citation (help) 
  13. Buckman-Owoo, Jayne (9 October 2021). "Social media for good: The Kafui Danku way". Graphic Online. Retrieved 13 November 2023. 
  14. Arthur, Portia. "Just A Number !!! Marriages with old men are the best - Kafui Danku". Archived from the original on 10 July 2018. Retrieved 13 June 2018. 
  15. "GOSSIP: Actress Kafui Danku & White Husband Are Splitting? - We've Just Spoken to Her About This... - Ghanacelebrities.com". 26 June 2016. Retrieved 13 June 2018. 
  16. Empty citation (help) 
  17. Buckman-Owoo, Jayne (9 October 2021). "Social media for good: The Kafui Danku way". Graphic Online. Retrieved 13 November 2023. 
  18. "Kafui Danku to support Kwashiokor Unit of Princess Marie Louise Hospital". GhanaWeb (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2018-05-10. Retrieved 2023-11-14.