Kahina

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Dihya
Queen of the Aurès

Dihya memorial in Khenchela, Algeria
Reign Early seventh century
Predecessor Kusaila
Father Tabat[1]
Died 703 AD (in battle)
Bir al-Kahina, Aurès[2]

Dihya, tí wọ́n ń pè ní Alkahina(Lárúbáwá: الكاهنة‎), jẹ́ ọbabìnrin ìlú Berber ti Aurès[2] bẹ́ẹ̀ náà ló jẹ́ olórí ẹ̀sìn àti olórí àwọn ológun tó tako Muslim conquest of the Maghreb, agbègbè ti wọ́n pè ní Numidia tẹlẹ̀ rí tí ó sì máa ń ṣégun àwọn ọmọ-ogun Umayyad nínú ogun Battle of Meskiana lẹ́yìn náà ni o di adarí fún gbogbo Maghreb láìsí olùdíjẹ tó takòó,[3][4][5][6] kí wọ́n tó ṣégun rẹ̀ ní ogun Battle of Tabarka. Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ sẹ́ntúrì kéje AD ni wọ́n bí i ó sì kú ní òpì sẹ́ntúrì kéje ti òde-òní Algeria.

Orísùn àti Ìpìnlẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orúkọ rẹ̀ gàngàn jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn orúkọ tó ní onírúurú ọ̀nà ìkọsílẹ̀ àti pípè: Daya, Dehiya, Dihya, Dahya tàbi Damya.[7] Nínú èdè Arabic ni ìpìlẹ̀ orúkọ rẹ̀ al-Kāhina ti wá(èyí tó túmọ̀ sí olúwo aríran). Èyí ni orúkọ tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ Mùsùlùmí nítorí àǹfàní tó ní láti rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́-iwájú.[8]

Nínú ẹ̀yà Jrāwa Zenata ní wọ́n bí i sí ní ìbẹ̀rẹ̀ séntúrì kéje.[9] Ọdún márùn-ún ni ó fi darí ìpínlẹ̀ Berber láti orí-òkè Aurès Mountains dé ilé ọlọ́ràá Gadames (695–700 AD). Ṣùgbọ́n àwọn Àràbó tí Musa bin Nusayr darí padal pèlú àwọn ọmọ oogun tó lágbára láti borí rẹ̀. Ó jà pẹ̀lú El Djem ṣùgbọ́n wọ́n pa nínú ìjà ní ẹ̀gbé kònga tó sì ń jẹ́ orúkọ̀ rẹ̀ Bir al KahinaAures.[10]

Oun tí a rí gbọ́ láti sẹ́ńtúrì kankàndìlógún ní Àdàkọ:Vague ni pé ọmọ agbègbè Jew ni tàbí pé ẹ̀yà rẹ̀ jẹ́ Judaized Berbers.[11] Gẹ́gẹ́ bih ohun ti al-Mālikī sọ, òrìṣà kan ló sì í lọ nínú ìrìàjò rẹ̀. Mohamed Talbi àti Gabriel Camps tú òrìṣà yìí sí akọni àwọn kìrìtẹ́nì kan, yálà tí Kírístì tàbí ti Wúdíá, tàbí ẹni mímọ́ kan tó ń dábòbò ọbabìnrin. M'hamed Hassine Fantar gbàgbọ́ pé akọni dúró gẹ́gẹ́ bí òrìsà Berber, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹlẹ́sìn Berber ni. Àmọ́, pé Dihya jẹ́ Kìrìtẹ́nì àhẹsọ lásàn ni.[8]

Àwọn ìtọ́kasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named father
  2. 2.0 2.1 Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid <ref> tag; no text was provided for refs named EB1306
  3. The History of Anti-Semitism, Volume 2: From Mohammed to the Marranos Leon Poliakov University of Pennsylvania Press
  4. Remarkable Jewish Women: Rebels, Rabbis, and Other Women from Biblical Times to the Present Emily Taitz, Sondra Henry Jewish Publication Society,
  5. History of North Africa: Tunisia, Algeria, Morocco: From the Arab Conquest to 1830 Charles André Julien Praeger
  6. The Jews of North Africa: From Dido to De Gaulle Sarah Taieb-Carlen University Press of America,
  7. See discussion of these supposed names by Talbi (1971).
  8. 8.0 8.1 Modéran, Yves (2005). "Kahena". Encyclopédie berbère. Edisud. pp. 4102–4111. doi:10.4000/encyclopedieberbere.1306. https://journals.openedition.org/encyclopedieberbere/1306. 
  9. Naylor, Phillip C. (2009) (in en). North Africa: A History from Antiquity to the Present. University of Texas Press. p. 65. ISBN 978-0292778788. https://books.google.com/books?id=a1jfzkJTAZgC. 
  10. Charles André Julien; Roger Le Tourneau (1970). Histoire de L'Afrique du Nord. Praeger. p. 13. ISBN 9780710066145. https://books.google.com/books?id=tYZyAAAAMAAJ. 
  11. See Hirschberg (1963) and Talbi (1971).