Kate Henshaw

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Kate henshaw)
Kate Henshaw
Ọjọ́ìbíKate Henshaw
19 Oṣù Keje 1971 (1971-07-19) (ọmọ ọdún 52)
Calabar, Nàìjíríà
Iṣẹ́Actress
Àwọn ọmọGabrielle Nuttall
Àwọn olùbátanAndre Blaze (cousin)

Kate Henshaw tí a tún mọ̀ sí Kate Henshaw-Nuttall ( wọ́n bi ní ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù keje, ọdún 1971)[1] jẹ́ gbajúmò eléré-orí ìtàgé.[2] Ní ọdún 2008, ó gbégbá orókè ní African Movie Academy Award fún ẹ̀dá ìtàn tí ó dára jù lọ nínú eré Stronger Than Pain.[3][4]

Ibere aye[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kate Henshaw jẹ́ ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Cross River, òun sì ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́rin tí òbí rẹ̀ bí. Ó lọ sí St Mary Private school ní Ajele, ní ìpínlè Èkó, lẹ́yìn èyí ni ó lọ sí Federal Government Girls College ní Calabar.[5]

Ó lo ọdún kan ni Ilé Ẹ̀kọ́ gíga, yunifásítì Calabar, níbi tí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ àtúnṣe, ó sì kó ìmọ̀ "Medical Microbiology" ni ilé ìwé Medical Lab Science , LUTH, ní ìpínlè Èkó.[6]

Henshaw tí ṣiṣẹ́ rí ní Bauchi State General Hospital, kí ó tó di eléré orí ìtàgé, ó ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí í àwòṣe ènìyàn, tí ó sì ṣe oríṣiríṣi ìpolówó lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, ọ̀kan lára wọn ni "Shield" , èròjà òórùn tó dára.

Awon Fiimu[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Above Death: In God We Trust (2003)
  • A Million Tears (2006)
  • My Little Secret (2006)
  • Stronger Than Pain (2007)
  • Show Me Heaven (2007)
  • Aremu The Principal (2015)[7]
  • Chief Daddy (2018) [8]
  • New Money (2018) [9]
  • The Ghost and the House of Truth (2019)[10]
  • 4th Republic (2019)
  • The Women (2018)

Àmìn-ẹ̀yẹ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Odun Amin-eye Abala Fiimu Abajade Itokasi
2017 Best of Nollywood Awards Best Supporting Actress –English The Women Gbàá [11]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "P.M. News". 2012: A Dramatic Year For Nigerian Artistes. 2012-12-28. Retrieved 2022-03-25. 
  2. "Kate Henshaw: Biography and five interesting facts to sabi about di award winning actor - BBC News Pidgin". BBC News Pidgin. July 19, 2021. Retrieved May 29, 2022. 
  3. "虎扑NBA-体育赛程". 虎扑NBA-体育赛程. 2018-01-30. Retrieved 2022-03-25. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. Ochuko, Rukevwe (2020-03-17). "Kate Henshaw Wins Best Actress In A Supporting Role At South Africa Rapid Lion Award". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2022-03-25. 
  5. Celebs, African (2019-07-19). "Nollywood Superstar Kate Henshaw is a year older today". Medium. Retrieved 2022-03-25. 
  6. Husseini, Shaibu (2021-07-24). "Kate Henshaw @ 50: Garlands for timeless diva - Nigeria and World News". The Guardian Nigeria News - Nigeria and World News. Retrieved 2022-03-25. 
  7. "'Aremu the Principal': Watch Kate Henshaw, Queen Nwokoye, Oyetoro Hafiz in trailer for new movie". Pulse Nigeria. Chidumga Izuzu. 20 May 2015. Retrieved 20 May 2015. 
  8. "Chief Daddy | Netflix". www.netflix.com. Retrieved 13 November 2019. 
  9. "New Money (2018 film)", Wikipedia, 24 October 2019, retrieved 13 November 2019 
  10. "The Ghost and the House of Truth". THISDAYLIVE. 28 September 2019. Retrieved 13 November 2019. 
  11. "BON Awards 2017: Kannywood’s Ali Nuhu receives Special Recognition Award". Daily Trust (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-11-23. Retrieved 2021-10-07.