Jump to content

Kayode Egbetokun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Kayode Egbetokun (tí wọ́n bí lọ́jọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án ọdún 1964)[1] jẹ́ Ọ̀gá-àgbà Ọ̀lọ́pàá Yànyàn ọmọ Ìpínlẹ̀ Ògùn lórílẹ̀-èdè Nigeria. Ààrẹ Bọlá Ahmed Tinubu ni ó yàn án lọ́jọ́ kọkàndínlógún oṣù kẹfà ọdún 2023 láti rọ́pò Ọ̀gá-àgbà Ọ̀lọ́pàá Yàn yàn-Àná, Usman Alkali Baba lẹ́yìn tí ó kéde yíyọ ọ́ kúrò nípò lọ́jọ́ kan náà.[2][3]

Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá Àgbà-yànyàn Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókùn dára pọ̀ mọ́ iṣẹ́ Ọ̀lọ́pàá gẹ́gẹ́ bí Cadet ASP lọ́jọ́ kẹta oṣù kẹta ọdún 1990. Ó kàwé gboyè Bachelor nínú imọ̀ ìsirò ní ilé-ìwé Ifáfitì ìjọba àpapọ̀ ti ìlú Èkó, University of Lagos. Ní ilé-ìwé yẹn bákan náà, ó kàwé gboyè Bachelor kan náà nínú Lámèyító ìmò-ẹ̀rọ (Engineering Analysis àti ìmò okoòwò. Ó tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì kàwé gboyè ọ̀mọ̀wé (PhD) nínú ìmọ̀ ìwàlálàáfíà àti ìpètùsáwọ̀ ní Ifáfitì Al-Hikmah University, ní ìlú Ìlọrin, ní Ìpínlẹ̀ Kwara.[4][5]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Yusuf, Kabir (2023-06-20). "PROFILE: Kayode Egbetokun: Nigeria’s new police chief". Premium Times Nigeria. Retrieved 2023-06-20. 
  2. Oyero, Kayode (2023-06-19). "FULL LIST: President Tinubu Appoints New Service Chiefs, Names Ribadu NSA". Channels Television. Retrieved 2023-06-20. 
  3. Oyero, Kayode (2023-06-19). "President Tinubu Removes All Service Chiefs, Others". Channels Television. Retrieved 2023-06-20. 
  4. Sanusi, Abiodun (2023-06-20). "Acting IG Egbetokun due to retire in 2024". Punch Newspapers. Retrieved 2023-06-20. 
  5. Anichukwueze, Donatus (2023-06-19). "Profile Of New IGP, Kayode Egbetokun". Channels Television. Retrieved 2023-06-20.