Jump to content

Kemi Badenoch

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Kemi Badenoch

Official portrait, 2022
Secretary of State for Business and Trade
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
7 February 2023
Alákóso ÀgbàRishi Sunak
AsíwájúGrant Shapps[lower-alpha 1]
President of the Board of Trade
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
6 September 2022
Alákóso ÀgbàLiz Truss
Rishi Sunak
AsíwájúAnne-Marie Trevelyan
Minister for Women and Equalities
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
25 October 2022
Alákóso ÀgbàRishi Sunak
AsíwájúNadhim Zahawi[lower-alpha 2]
Secretary of State for International Trade
In office
6 September 2022 – 7 February 2023
Alákóso ÀgbàLiz Truss
Rishi Sunak
AsíwájúAnne-Marie Trevelyan
Arọ́pòOffice abolished
Junior ministerial offices
Minister of State for Local Government, Faith and Communities
In office
16 September 2021 – 6 July 2022
Alákóso ÀgbàBoris Johnson
AsíwájúLuke Hall
Arọ́pòPaul Scully
Minister of State for Equalities[lower-alpha 3]
In office
14 February 2020 – 6 July 2022
Alákóso ÀgbàBoris Johnson
AsíwájúThe Baroness Williams of Trafford
Arọ́pòAmanda Solloway
Exchequer Secretary to the Treasury
In office
13 February 2020 – 16 September 2021
Alákóso ÀgbàBoris Johnson
AsíwájúSimon Clarke
Arọ́pòHelen Whately
Parliamentary Under-Secretary of State for Children and Families
In office
27 July 2019 – 13 February 2020
Alákóso ÀgbàBoris Johnson
AsíwájúNadhim Zahawi
Arọ́pòVicky Ford
Member of Parliament
for Saffron Walden
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
8 June 2017
AsíwájúAlan Haselhurst
Majority27,594 (43.7%)
Member of the London Assembly
as the 4th Additional Member
In office
5 May 2016 – 8 June 2017
AsíwájúGareth Bacon
Arọ́pòSusan Hall
Member of the London Assembly
as the 9th Additional Member
In office
16 September 2015 – 5 May 2016
AsíwájúVictoria Borwick
Arọ́pòShaun Bailey
Àwọn àlàyé onítòhún
Ọjọ́ìbí
Olukemi Olufunto Adegoke

2 Oṣù Kínní 1980 (1980-01-02) (ọmọ ọdún 44)
Wimbledon, London, England
Ẹgbẹ́ olóṣèlúConservative
(Àwọn) olólùfẹ́
Hamish Badenoch (m. 2012)
Àwọn ọmọ3
Alma mater
Occupation
  • Politician
  • software engineer
  • consultant
  • banker
SignatureFáìlì:Kemi Badenoch signature.svg
Websitekemibadenoch.org.uk

Olúkẹ́mi Olúfúntọ́ Badenoch ( /ˈbeɪdnɒk/ BAYD-nok; Nee Adegoke; born 2 January 1980)[1] jẹ́ gbajúmọ̀ òṣèlú ọmọ orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì, ó jẹ́ ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ní ẹkùn ìdìbò Saffron Walden láti ọdún 2017 títí di àkókò yìí. Ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Conservative Party, ó ti fìgbà kan jẹ́ mínísítà kéréje fún ìjọba-ìbílẹ̀, ẹ̀sìn àti àdúgbò, àti mínísítà kéréje fún orí-ò-jorí, bákan náà ó jẹ́ igbá-kejì sí Liz Truss láàárín ọdún 2021 sí 2022.[2][3] Àwọn òbí rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nigeria bí i Badenoch ní ìlú WimbledonLondon. Ó lo ìgbà èwe rẹ̀ ní Amẹ́ríkà àti Ìlú Èkó lórílẹ̀ èdè Nigeria. Ó padà sí orílẹ̀ èdè United Kingdom nígbà tí ó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún. Lẹ́yìn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀-ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà ní University of Sussex, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ọrọ-ẹ̀rọ ní Logical. Bákan náà ló lọ ṣiṣẹ́ ní ilé-ìfowópamọ́ Royal Bank ní orílẹ̀ èdè Scotland gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ẹ̀rọ kọ̀m̀pútà, kí ó tó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Alájọdarí níCoutts, lẹ́yìn èyí, ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí adarí ní ilé-iṣẹ́ oníròyìn, The Spectator.[4][5]

Lọ́dún 2012, Badenoch fìdí rẹmi nínú ìdìbò fún ilé aṣòfin Ìpínlẹ̀ London. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, ó gbégbá orókè nínú ìdìbò kan náà nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin, London Assembly. Badenoch jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alágbátẹrù Brexit. Wọ́n dìbò yàn án gẹ́gẹ́ bí aṣojú-ṣòfin ti Saffron Walden nínú ìdìbò 2017. Lẹ́yìn tí Boris Johnson di Ààrẹ, (Prime Minister) ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́dún 2019, wọ́n yan Badenoch gẹ́gẹ́ bí Mínísítà fún ètò àwọn ọ̀jẹ̀ wẹ́wẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso akọ̀wé kékeré fún ilé iṣẹ́ eleto àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ àti ètò ẹbí. Lẹ́yìn èyí, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé alámójútó Exchequer Secretary to the Treasury àti Parliamentary Under-Secretary of State for Equalities lọ́dún 2020. Lọ́dún 2021, wọ́n yàn án ní mínísítà kéréje fún ìjọba-ìbílẹ̀, ẹ̀sìn àti àdúgbò, àti mínísítà kéréje fún orí-ò-jorí

Lọ́dún 2022, ó kọ̀wé fipò sílẹ̀ láti du ipò Ààrẹ Orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì lábẹ́ àsíyá ẹgbẹ́-òṣèlú Conservative Party, lẹ́yìn tí Ààrẹ-àná, Boris Johnson kọ̀wé fipò sílẹ̀.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. As Secretary of State for Business, Energy and Industrial Strategy.
  2. As Minister for Equalities.
  3. As Parliamentary Under-Secretary of State from 2020 to September 2021.
  1. Brunskill, Ian (19 March 2020). The Times guide to the House of Commons 2019: the definitive record of Britain's historic 2019 General Election. pp. 319. ISBN 978-0-00-839258-1. OCLC 1129682574. http://worldcat.org/oclc/1129682574. Retrieved 23 June 2021. 
  2. "UK Prime Minister twitter". Twitter (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2022-09-06. 
  3. "Sunak reshuffle: Shapps named energy secretary in department shake-up". BBC News. 7 February 2023. Retrieved 7 February 2023. 
  4. McFadden, Brendan (8 July 2022). "Former equalities minister Kemi Badenoch announces Tory leadership bid". inews.co.uk (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 8 July 2022. Retrieved 8 July 2022.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  5. "Conservative leadership latest: Badenoch out as Sunak wins fourth Tory vote". BBC News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 19 July 2022. Retrieved 2022-07-19.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)