Jump to content

Kenkey

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Kenkey
Kenkey and ground pepper with sardine
Alternative nameskɔmi pronounced (kormi),
TypeSwallow, dumpling
Place of originGhana
Main ingredientsGround corn
Àdàkọ:Wikibooks-inline 
Obìnrin tó ń se fante kenkey

Kenkey (tí a tún mọ̀ sí kɔmi, otim, kooboo tàbí dorkunu) jẹ́ oúnjẹ òkèlè tí ó fara jọ búrẹ́dì láti agbègbè Ga and Faninhab ti Ìwọ-Oòrùn Áfíríkà , tí wọ́n sábàá máa ń jẹ pẹ̀lú ọbẹ̀ crudaiola àti ẹja gbígbẹ, ọbẹ̀ tàbí ata.

Kenkey máa ń di ṣíṣe pẹ̀lú àgbàdo nípa rírẹ àgbàdo sínú omi fún bíi ọ̀sẹ̀ kan, kí ó tó di pé wọ́n di lílọ̀ tí wọ́n sì di rírẹ pẹ̀lú omi sí dóòfù.[1] Wọ́n máa ń fi dóòfù yìí lára balẹ̀ láti fa omi mu fún ọjọ́ mẹ́rin sí ọ̀sẹ̀ kan síwájú kí dóòfù náà tó di ṣíṣè.

Àwọn agbègbè níbi tí wọ́n ti ń jẹ Kenkey ni Ghana, eastern Côte d'Ivoire, Togo, western Benin, Guyana, àti Jamaica. Ó sábàá máa ń di ṣíṣe láti ara àgbàdo, gẹ́gẹ́ bí sadza àti ugali. Ó jẹ́ mímọ̀ káàkiri gẹ́gẹ́ bí kɔmi (pípè ní kormi) láti ọwọ́ àwọn Gas tàbí dokono láti ọwọ́ àwọn Akans ní Ghana. Ó tún jẹ́ mímọ̀ sí gẹ́gẹ́ bí dokunoo, dokono, dokunu, blue drawers, àti tie-a-leaf. Ní Guyana, wọ́n ń pè é ní konkee.[2] Ní Trinidad wọ́n ń pè é ní "paime" (pípè ní pay-me) tí ó sì yàtọ̀ ní pé kò ní ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà ṣùgbọ́n tí ó lè ní àgbọn, pumpkin àti/tàbí raisin. Àsìkò ọdún Kérésìmesì ni wọ́n sábàá máa ń jẹ oúnjẹ náà.[3] Nínú oúnjẹ Caribbean, ó máa ń di ṣíṣe pẹ̀lú ọkà bàbà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbagbà, ọ̀gẹ̀dẹ̀ aláwọ̀ ewé, ànàmọ́ (ẹ̀yà ti Asante àti Jamaican ,èyí tí ó wá láti ẹ̀yà ti Asante) tàbí ẹ̀gẹ́ , tí a fi ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ wé. Oúnjẹ náà di rírí láti ara ìṣe ìdáná ilẹ̀ Áfíríkà.

[4][5]

Fante kenkey

Yíyátọ̀ sí ugali, ṣíṣe kenkey níse pẹ̀lú jíjẹ kí àgbàdo náà fún omi gbẹ síwájú ṣíṣè. Fún ìdí èyí, ìgbáradì máa ń gba ọjọ́ díẹ̀ láti lè jẹ́ kí dóòfù náà wú. Àgbàdo máa ń di pípò pọ̀ pẹ̀lú sítáàsì, omi sì máa ń di fífi sí i títí ó máa fi dán tí dóòfù ó sì fi di ṣíṣe. Ó máa ń di bí ò, yóò sì di fífi sílẹ̀ ní ààyè tí ó lọ́wọ́rọ́ fún wíwú náà láti wáyé. Lẹ́yìn wíwú, Kenkey náà máa ń di ṣíṣè díẹ̀, wọn á sì fi ewé ọ̀gẹ̀dẹ̀ bò ó, aṣọ àgbàdo tàbí irin tẹ́ẹ́rẹ́, yóò sì di ṣíṣe. Orísìírísìí ẹ̀yà Kenkey ló wà, gẹ́gẹ́ bí Kenkey ti Ga àti Fante.[6] Kenkey ti Ga wọ́pọ̀ dáadáa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè Ghana.

Kenkey ti Ice jẹ́ oúnjẹ tí a ṣe láti ara Kenkey tí a pò pọ̀ pẹ̀lú omi, súgà, mílíìkì, àti yìnyín.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. Atter, Amy; Ofori, Hayford; Anyebuno, George Anabila; Amoo-Gyasi, Michael; Amoa-Awua, Wisdom Kofi (2015). "Safety of a street vended traditional maize beverage, ice-kenkey, in Ghana". Food Control 55: 200–205. doi:10.1016/j.foodcont.2015.02.043. 
  2. "Ghana: Kenkey". 196 flavors (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2019-06-21. Retrieved 2020-06-04. 
  3. "Trinidad Paime: A Favourite Christmas Treat". SimplyTriniCooking.com. Retrieved 2024-05-19. 
  4. Jamaican Cooking: 140 Roadside and Homestyle Recipes. Macmillan USA. 1997. ISBN 9780028610016. https://books.google.com/books?id=BIBjAAAAMAAJ&q=Dokunoo. 
  5. "Regional Dishes". touringghana. Archived from the original on 10 August 2013. Retrieved 9 August 2013.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  6. "KENKEY". Ghanaweb. Retrieved 9 August 2013.