Killie Campbell

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

 

Killie Campbell
Ọjọ́ìbíMargaret Roach Campbell
(1881-09-09)9 Oṣù Kẹ̀sán 1881
Mount Edgecombe
Aláìsí28 September 1965(1965-09-28) (ọmọ ọdún 84)
Durban
Iṣẹ́Collector of Africana

Dokita Margaret Roach 'Killie' Campbell (tí wọ́n bí ní ọdún 1881 tó sì ṣàláìsí ní ọdún 1965) jẹ́ olùṣàtójọ àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé ilẹ̀ Africa. Ó fún University of Natal ní awọn àkójọ rẹ̀, tó ti wá di Killie Campbell Africana Library báyìí.[1] Campbell jẹ́ ọmọbìnrin kejì ti olóṣèlú Natal àti Sir Marshall Campbell .

Ètò ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó kàwé ní St. Anne's Diocesan College ní Hilton, KwaZulu-Natal àti ní St. Leonard's School ní ìlú Scotland.

Àwọn iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ọdún 1939 Killie sọ ọ́ di mímọ̀ pẹ́, “Àkójọpọ̀ àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé òun dá́ lórí àwọn ìwẹ́-ìrìn àjọ̀ ọjọ́ pípẹ́, ìwé lórí ìtàn, ìtàn ìgbésíayé àwọn ènìyàn, àti àwọn ìtàn àtijọ́.” Nígbà tí ó ń ṣe àpejúwe àwọn àkójọpọ̀ rẹ̀ nínú àyọkà tí wọ́n ṣàtẹ̀jáde ní oṣù kẹsàn-án ọdún 1945, ó kọ pé, “Yàrá ìkàwé náà ní tó ìwé ọ̀kẹ́ kan (20,000), mo sì ti ṣiṣẹ́ pàtàkì lórí ìtàn Bantu." [2]

Ìdá́lọ́lá àti àwọn àṣesílẹ̀ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

University of Natal fún Campbell ní àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 1950, bẹ́ẹ̀ sì ni University of Witwatersrand fún ni àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 1954. Ó sì tún gba àmì-ẹ̀yẹ láti jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ ní South African Library Association ní ọdún 1958. City of Durban fun ní àmì-ẹ̀yẹ ní ọdún 1964. [2]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Campbell 2000, p. 269-.
  2. 2.0 2.1 Duggan 1981.