Koisaanu

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Khoisan
San tribesman from Namibia
Regions with significant populations
Southern Africa
Èdè

Khoisan languages

Ẹ̀sìn

Animist, Muslim[1]

Ẹ̀yà abínibí bíbátan

perhaps Sandawe

Oju=iwe kiini[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

OLOFNSAO OLUKEMI M.

ÀWON EBÍ ÈDÈ KHOISAN

Ìfáàrà

Ebí èdè Khoisan yìí ni ó kéré jù lo nínú àwon ebí èdè gbogbo tí ó wà ní Áfíríkà. Gégé bí Greenberg (1963a) ti so, ó ní àwon ni wón dúró fún èyí tí ó kéré jù lo nínú èdè Áfíríkà. ÌPÌLÈ ORÚKO ÈDÈ YÌÍ A mu orúko yìí jáde láti ara orúko egbé Khoi-Khoi ti Gusu ile Afirikà (South Africa) àti egbé san (Bushmen) ti Namibia. A máa ń lo orúko yìí fún Orísìírísìí àwon èyà tí wón jé pé àwon gan-an ni wón kókó jé olùgbé ilè south Africa kí awon Bantu tó wá, kí àwon òyìnbó ilè Geesi (Europe) sì tó kó won lérù. Orísìírísìí àwon onímò ni won ti sise lórí orúko yìí – Khoisan.Tan Gùldemann ati Rainer Vossen sàlàyé nínú isé rè pé Leonardt Schulze 1928 ni o mu orúko yìí jáde láti ara Hottentot’ tí o túmò sí Khoi ti o sì tún túmò sí ‘person’ (ènìyàn) àti ‘san’ tí ó túmò sí ‘forager’. Léyìn èyí ni onímò ìjìnlè nípa èdá àsà, ìgbàgbó àti ìdàgbàsókè omonìyàn, anthropologist Schapera (1930) tún wá fè orúko yìí lòjù séyìn nípasè ‘Hottentot’àti ‘Bushman’ gégé bí èyà, (racia) àsà (cultural) àti ìmò èdá èdè. (Linguistic). Àwon orúmò mìíràn tí wón jé gégé bí egbé keta ti wón tún sisé lé orúko yìí lórí ni Kolnler (1975, 1981) sands (1998) àti Traill (1980, 1986). Won pinnu láti lo orúko náà Khoisan gégé bí olúborí fún àwon èdè tí kìí se ti Bantù tí kì í sì í se èdè Cushitic. Àwon onímò akíólójì fi han wí pé nnkan bí egbèrún lónà ogófa odún séyìn ni awon ènìyàn Khoisan ti fara hàn. Èyí fi han pé lódò àwon àgbà láèláè nìkan ni a ti lè máa gbó èdè Khoisan nìkan báyìí. Bí èdè Khoisan tilè farajora nínú ètò ìró, gírámà tirè yàtò gédégbé. Àìsí àkósìlè ìtàn àwon èdè wònyí mú kí o nira díè láti so ìfarajora awon èdè yìí sí ara àti sí àwon èdè adúláwò tí ó kù. Lóde àní, Ilè (South Western Africa) gúsu-ìwò òòrùn Áfíríkà títí dé àginjù kàlàhárì (Kalaharì Desert), láti Angola de South Africa àti ní apákan ilè Tanzania nìkan ní wón ti ń so èdè Khoisan. Edè Hadza àti Sandawe ní ilè Tanzania ni a sáábà máa ń pè ní Khoisan súgbòn wón yàtò nípa ibùgbé àti ìmò èdá èdè sí ara won. A wá lè so pé nínú gbogbo èdè àgbáyé, èdè Khoisan wà lára àwon èdè tí àwon onímó èdè kò kobiara sí tí a kò sì kó èkó nípa rè.

ÌPÒ TÍ ÈDÈ YÌÍ WÀ

Èdè Khoisan yìí gégé bí a ti so síwájú ń dín kù síi lójoojúmó ni. Béè ni ó sì ń di ohun ìgbàgbé. Ohun tí ó fa èyí ni pé àwon tí wón ń so àmúlùmálà èdè Khoisan bèrè sí í so èdè mìíràn tí ó gbilè ní agbègbè won; wón sì dékun kíkó àwon omo won ní èdè abínibí won. Òpò àwon èdè wònyí ni kò ní àkósilè kankan tí ó sì fíhàn pé sísonù tí àwon èdè wònyí sonù, kò lè ní àtúnse. Ó jé ohun tí ó nira díè láti so pé iye àwon ènìyàn kan pàtó ni wón ń so èdè Khoisan. Bí ó tilè jé pé a kò mo ohun tí ó selè sáájú kí àwon Òyìnbó tó gòkè bò, a kò sì mo ohun tí ó selè ní gbogbo àkókò tí àwon Òyìnbó ń sètò ìjoba, béè sì tún ni pé ìwònba la lè so mo nípa ohun ti ó ń sele ní lówólówó yìí pèlú. Sùgbón àkosílè fi hàn pé, ní bíì egbèrún odún méjì séyìn, iye nónbà tí wón ko sílè kò seé tèlé mó; àkosílè so wí pé egbèrún lónà ogófà sí egbèrún lónà Igba (120,000 – 200,000) ni won, sùgbón èyí ti di ohun àfìséyìn bí eégún fí aso. Won kò tó béè mó. Díè lára àwon èdè khoisan àti iye àwon tí wón ń so ó.


EDE, IYE ÀWON TI Ń SO, ILÚ,

Sandare, 40, 000, Tanzania

Haillom (San), 16,000, Namibia,

Name (Khoekhoegowab) 233,701 Namibia, Botswana, South Africa

Suua , 6,000, Botswana

Tsoa. 5,000, Botswana

//Ani , 1,000, Botswana

Gana, 2,000, Botswana

Kxoe 10,000, Namibia, Angola, Botswana South Africa, Zambia

//Gwi, 2,500 , Botswana

Naro, 14,000, Botswana, Namibia =Ikx’aull’ein 2,000, Namibia, Botswana

Kung-Ekoka, 6,900, Botswana, Angola, South Africa.

Oju-iwe keji[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

IHUN EDE KHOISAN

ÈTÒ ÌRÓ

Àwon èdè Khoisan kò sàì ní ìfarajora nínú ètò ìrò. Ó dá yàtò gédégbè sí àwon èdè ilè Áfíríkà yòókù, ó sì jé òkan lára àwon èdè tí ó nira.

FAWELI

Òpò àwon èdè Khoisan wònyí ni ó ń lo fáwélì márùn ún - /i/, /e/, /a/, /o/, /u/ tí a sì lè pè pèlú àwon orísìí àbùdá wònyìí bíi, ìránmú, (nasalization) ìfi káà-òfun-pè (pharyngealization) ati orísìí àmúye ohùn bíi mímí ohun (breathy voice) ati dídún ohùn (Creaky voice) tí yóò sì mú bí i orísìí ìró fáwélì bí i ogójì jáde.

KÓŃSÓNÁNTÌ:-

(Clicks) kílíìkì

Kílíìkì ni a ń pe àwon kóńsónántì won; títí kan àwon àfeyínpè (dential), àfèrìgìpè, (alveolar), afàjàfèrìgìpè (alveo-palatal), afègbé-enu-pè (lateral) àti kílíìkì afètèpè (bilabial Chick). Sandawe àti àwon Hadza tí ilè Tanzania ń lo àfeyínpè (dental ) afèrìgìpè (alveolar) àti kílíìkì afègbé-enu-pè (lateral clicks). Pèlú gbogbo àheso òrò títí di àkókò yìí orísun kílíìkì èdè Khoisan kò tíì yéni.

Àpeere:-

- Kiliiki Àfeyínpè – A máa ń pe èyí nípa gbígbé ahón sí èyìn eyín iwájú. “tsk”

- Kílíìkì Afèrìgìpè – Ó máa ń dún bí ìgbà tí a bá sí ìdérí ìgò nípa gbígbé ahón sí èyìn eyín iwájú.

- Kílíìkì Afàjàfàrìgìpè – Ó máa ń dún nípa gbígbé ahón sílè kúrò lára àjà enu.

- Kílíìkì Afègbé-enu-pè – ó máa ń dùn gégé bí ìró ti à ń lò lédè Gèésì láti mú kí esin kánjú.

- Kílíìkì Afètépè máa ń dún nípa kíkanra ètè méjèèjì, tí a sì tún sí i sílè ní kíá, gégé bí ìró ìfenukonu ni èyí se máa ń dún.

Òkòòkan àwon kílíìkì wònyí ló lè ní Kíkùnyùn-ùn, (Voicing) ríránmú (nasality), “aspiration” ati “ejection”. Láti le mú kí á ní àgbéjáde orísìírísìí kílíìkì. Àwon orísìírísìí kílíìkì wonyi ló mú kí èdè Khoisan yàtò. Àpeere nínú èdè Nama, Ogún ni kílíìkì tí wón ń lò nígbà tí wón n lo métàlélógórin nínú ède Kxoe tí ó jé òkan lára èdè Khoisan. Ní àfíkún, àádórùn-ún ònírúrú kóńsónántì kílíìkì ni wón n lo ni Gwi tí òhun náà jé òkan lára èdè Khosian wònyí. Àpeere Kílíìki Nama

SÍLÉBÙ

Gbogbo àwon kóńsónántì Kílíìkì àti èyí tí kìí se kílíìkì ló máa ń fara hàn ní ìbèrè òrò tí fáwélì sì máa ń tèlé e. Ìwònba kóńsónántì bí àpeere /b/, /m/, /n/, /r/, àti /l/ ló lè je yo láàrín fáwélì, díè sì lè farahàn ní èyìn òrò.

ÌRÓ OHÙN

Àwon èdè Khosan máa ń sàfihàn orísìírísìí ìró ohùn, bí àpeere, Jul’hoan ní ipele ohun àárún orísìí mérùn, ó sì ní ipele ohun òkè kan.

GIRAMA

Òrò àti ìhun gbólóhùn àwon èdè Khoisan yàtò síra láàrin ara won.

ÒRÒ ORÚKO

Ìsòrí méta ni òrò arúko Khoisan pín sí; bí a bá wòó, nípasè jenda, ako, abo àti àjoni ni ò pín sí. Nínú Kxoe, fún àpeere, jéńdà nínú òrò-orúko aláìlémìí tún máa ń ní nnkan se pèlú ìrísí, bi àpeere, ako ní í se pèlú gígùn, tí tò si tóbi, nígbà tí abo ní í se pèlú nnken kúkúrú, gbígbòòrò tí kó sì tóbi òrísìírísìí mófíímù ni wón fi ń parí òkòòkan àwon jéńdà wònyí.

Àpeere láti inú èdè Nama.

Khoisan , English, Yoruba ,

Khoe-b, Man , Okùnrin ,

Khoe-s, Woman, Obinrin ,

Orísìírísìí nómbà méta ni wón ní, àwon ní eyo, oníméjì àti òpò.

NÓMBÀ Apeere lati inu èdè Naro

Male (Ako), Female (Abo), Common (Ako/Abo)

SG, ba , sa _________ Dual , tsara , sara, Khoara

PL llua dzi na

ÒRÒ-ÌSE

Àbùdá gírámà tí ó sáábà máa ń je yo nínú àwon èdè Khoisan ni lílo òrò-ise àkànmónúko (verb compound) nígbà tí èdè Gèésì ń lo òrò atókùn tàbí òrò-ise kan (single verb) Àpeere

English, Khoisan, Enter go + enter.

Àsìkò (Tense)

Èrún ni a máa ń lò láti fi àsìko hàn nínú èdè KhoeKhoe àti nípa lílo àfòrò eyin nínú ede Kxoe, Buga ati //Ani Ninú àwon èdè Kalahari East Kxoe, Àfòmó èyìn ló ń fi ìsèlè ti o ti Koja hàn (Past Tense), ohun tó ń selè lówó tí ó lòdì ati jèróndì hàn nígbà tí ìsèlè lówólówó àti ti ojó iwájú ń lo Èrún. Béè náà lomó sorí nínú èdè Naro, G//ana, G/ui àti ‡Haba.

IBÁ ÌSÈLÈ

Mana nìkan ni ó ń lo ibá ìsèlè gégé bí ònà ìsèdá (Morphological Category) ó sì ya ibá ìsèlè asetán sótò sí àìsetán


IYISODI

Èrún tàbí àfòmó èyìn ni won n lo fún ìyísódì (Khoekhoe tam; G//ana G/ui àti ‡Haba tàmátema) n lò èrún fún ìyísódì nígbà tí (kxoe //Am. Buya-bé) n lo afomo eyin, nígbà mìíràn wón n lo méjèèjì. Ètò Òrò Ètò òrò tí àwon èdè Khoisan ti à ń so wònyí máa ń lò ni (Svo-Subject-Verb-Object) Olùwà òrò-ìse àti àbò tàbí (Sov-Suject-Object-verb).

Òrò Èdè (Vocabulary)

Àfihàn ìgbésí ayé àwon olùso èdè Khoisan ni òrò-èdè (Vocabulary) won jé. Ní ìwòn ìgbà tí àwon olùso èdè wònyí ń gbé pò pèlú àwon ìsèdá mìírà, èyí mú kí wón ní àwon òrò-èdè tí ó súnmó ode síse, eranko, Kóríko àti béè béè lo.

ÀKÓSÍLÈ

Òpò àwon èdè wònyí ni kò ni àkosílè sùgbón Nama ati Naro ni àkosílè àti ohun èlò ìkóni. Nama ní pàtàkì ti wà ní àkosílè láti ojó pípé.