Korto Reeves Williams

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Korto Reeves Williams jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́-obìnrin ti orílẹ̀-èdè Liberia. Òun ni olùdarí àti alákòóso ẹ̀tọ́ obìnrin fún ActionAid Liberia, bẹ́ẹ̀ sì ni ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ìgbìmọ̀ Urgent Action Fund (Africa), Liberia Feminist Forum àti African Feminist Forum.[1] Ó ṣàwárí èrèdí-ìwásáyé rẹ̀ látàrí iṣẹ́ ìjà-fẹ́tọ̀ọ́-obìnrin.[2]

William's sọ ọ́ di mímọ̀ pé: "Kí wọ́n tó lè ẹgbẹ́ àwọn obìnrin tó dá dúró, wọ́n máa nílò ọ̀pọ̀ obìnrin tó máa farahàn gẹ́gẹ́ bíi ajà-fẹ́tọ̀ọ́-obìnrin ní gbangba. A nílò láti ṣe ìrànwọ́ fún àkọsílẹ̀ lítíréṣọ̀ tó dá lórí ìjà-fẹ́tọ̀ọ́-obìnrin. A sì ní láti ṣètò ìdásílẹ̀ ẹgbẹ́ ajà-fẹ́tọ̀ọ́-obìnrin kárí ayé láti máa ṣe ìkéde àti kí wọ́n ba lè dá sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin. Nígbàkigbà tí mo bá ṣalábàápàdé obìnrin tó ṣe tán láti dojú kọ àwọn ìlànà tó tàpa sí ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin, orí mi máa ń wú.!" [3]

Ètò ẹ̀kọ́[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Williams gboyè master's nínú ẹ̀kọ́ Sustainable Development láti School of International Training (tó ti wá di SIT Graduate Institute) ní Vermont, United States.[4]

Iṣẹ́ tó yàn láàyò[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Williams ni alákòóso ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin fún ActionAid, ní Liberia,[5] àti olùdarí ẹgbẹ́ ní ìlú náà.[6]

Nígbà tó ṣe ìbẹ̀wò sí ìlú Liberia ní oṣù kejì ọdún 2011, òṣèrébìnrin, ìyẹn Emma Thompson ṣàkíyèsí èrò UN bí ó ṣe ń ti pápá ọkọ òfuurufú bọ̀, ó sì bá Williams sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, ìyẹn sì sọ fún pé òun fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ ní UN, nítorí wọn ò fàyè gba àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn tó jẹ́ ọ̀dọ́.[6]

Lára àwọn ìwé àtẹ̀jáde rẹ̀ ni Beyond Mass Action: A Study Of Collective Organizing Among Liberian Women Using Feminist Movement Perspectives.[1] Williams has frequently contributed to ActionAid International's magazine, Common Cause, as well as a book, Voice, Power and Soul: A Portrait of African Feminists.[4]

Ní oṣù kẹsàn-án ọdún 2017 op-ed in The Bush Chicken (tí ó tún farahàn gẹ́gẹ́ bí Africa ní LSE blog post lórí ẹ̀ka ayélujára ti London School of Economics), Williams (àti òǹkọ̀wé kejì, ìyẹn Robtel Neajai Pailey) sọ̀rọ̀ nípa Ààrẹ ìlú Liberia, ìyẹn Ellen Johnson Sirleaf, tí ó jẹ́ Ààrẹ-bìnrin àkọ́kọ́ ti ilẹ̀ Africa.[7][8] Wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ pé láàárín ọdún méjìlá tó lò, "kò kópa kankan láti fi àwọn obìnrin sí ipò tó máa fún wọn ní àǹfààní láti díje dupò ìjọba".[8]

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. 1.0 1.1 "Korto Reeves Williams". www.aljazeera.com. Retrieved 6 November 2017. 
  2. "Korto Reeves Williams » African Feminist Forum". African Feminist Forum (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2016-03-25. Retrieved 2020-02-28. 
  3. "Korto Reeves Williams » African Feminist Forum" (in en-US). African Feminist Forum. 2016-03-25. http://www.africanfeministforum.com/korto-reeves-williams/. 
  4. 4.0 4.1 Iriga, Masterpiece Fusion-Martin. "Urgent Action Fund Africa". urgentactionfund-africa.or.ke. Archived from the original on 7 November 2017. Retrieved 6 November 2017. 
  5. "Korto Reeves Williams - African Feminist Forum". africanfeministforum.com. 25 March 2016. Retrieved 6 November 2017. 
  6. 6.0 6.1 Thompson, Emma; Agaba, Tindy (6 March 2011). "Liberia: A land divided". Retrieved 6 November 2017 – via www.theguardian.com. 
  7. "Is Liberia’s Sirleaf really standing up for women? #LiberiaDecides". lse.ac.uk. 6 September 2017. Retrieved 6 November 2017. 
  8. 8.0 8.1 "OP-ED: Is Liberia’s Sirleaf Really Standing Up for Women?". bushchicken.com. Retrieved 6 November 2017.