Kunle Adeyanju
Kúnlé Adéyanjú ti a tún mọ si “Ọkàn bíi Kìnìún”, jẹ́ ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ogbontarigi akọṣẹmọṣẹ nipa alùpùpù wiwa si ni pẹlu. Bakanna, oun ni Aare aṣẹṣẹ yan fun awọn ẹgbẹ Alaanu ti a n pe ni Rotary Club ni agbegbe Ìkòyí, ni orilẹ-ede Nàìjíríà[1][2]. Kunle Adeyanju ti ṣe apejuwe ara rẹ gẹgẹbi alaya gbangba ti ohunkohun ko le dẹru ba. O ti gun oke ti o ga ju ni ilẹ alawọ dudu afrika ti a n pe ni Oke Kilimanjaro lẹẹmeji[3]. Ni akoko kan Kunle ti wa alùpùpù lati ilu Eko lọ si ilu Accra ni orilẹ-ede Ghana laarin ọjọ mẹta. Ni bayii, oun ni ẹni akọkọ tí yoo gun alùpùpù lati ilu Ọba (Ilu Lọndọnu) sí ilu Eko, ni orilẹ-ede Naijiria[4]. Irinajo naa gba a ni ọjọ mọkan-le-logoji; orin iwọn ibusọ ẹgbẹrun mẹtala, ó gba orilẹ-ede mọkanla ati ilu mọkan-le-lọgbọn ki o to pari irinajo naa si ilu Eko, ni orilẹ-ede Nairjiria. Ohun to ṣe okunfa iru irinajo bi eyi ni ipolongo igbogun ti arun rọmọlapa-rọmọlẹsẹ ti Kunle Adeyanju ngbiyanju lati fi ko owo jọ lorukọ ẹgbẹ Alaanu Rotary; arun rọmọlapa-rọmọlẹsẹ yii ko tii kasẹ nilẹ ni ilẹ alawọ dudu Afrika bi o tilẹ jẹ wipe a ti gbiyanju lati paarẹ ni ọdun 2020. Kunle Adeyanju sọ wipe oun pinnu lati gbogun ti arun rọmọlapa-rọmọlẹsẹ yii nitori ọrẹ timọtimọ ni igba ewe ti arun yii ṣeku pa. O woye wipe ti arun rọmọlapa-rọmọlẹsẹ yii ko ba kọlu ọre oun, o ṣeeṣe ki o wa láyé di òni yii.
̀Awọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ https://edition.cnn.com/travel/amp/kunle-adeyanju-london-to-lagos-lgs-cmd-intl/index.html[Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
- ↑ https://tribuneonlineng.com/my-scariest-moment-was-when-i-ran-out-of-water-in-mauritania-adeyanju-london-to-lagos-biker/
- ↑ https://www.bbc.com/yoruba/media-61623688
- ↑ https://businessday.ng/amp/news/article/lagos-to-london-rider-adeyanju-lands-in-lagos/