Lola Alao

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Lọlá Àlàó)

Lola Rhodiat Alao (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọ̀kàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1970) jẹ́ òṣeré sinimá àgbéléwò ọmọ Ìgbìrà ní ìpínlẹ̀ Kogí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Gẹ́gẹ́ bí òṣèré, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ.[1] [2]

Ìgbà èwe rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ìgbà èwe rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà ni Army Children School, Ìlọrin. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Sóbí Government School. Ó kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ to wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, (University of Lagos). Lọlá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà pẹ̀lú ère àṣàfihàn lórí tẹlifíṣọ̀nnù tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ripples". Lẹ́yìn èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni sinimá àgbéléwò ló ti kópa. Òun fún ara rẹ̀ tí ṣẹ olóòtú sinimá tó ju ọgbọ̀n lọ.[3] [4]

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Lola Alao Biography - MyBioHub". MyBioHub. 2016-07-06. Retrieved 2019-11-24. 
  2. Published (2015-12-15). "It’s nobody’s headache if I change my religion –Lola Alao". Punch Newspapers. Retrieved 2019-11-24. 
  3. "Lola Alao Biography - Wikipedia - Profile". 360dopes. 2018-08-10. Retrieved 2019-11-24. 
  4. ""I was born into a Muslim home" actress clears air on conversion". Pulse Nigeria. 2016-07-22. Retrieved 2019-11-24.