Lola Alao
Ìrísí
Lola Rhodiat Alao (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kọ̀kàndínlógún oṣù Kejìlá ọdún 1970) jẹ́ òṣeré sinimá àgbéléwò ọmọ Ìgbìrà ní ìpínlẹ̀ Kogí lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Gẹ́gẹ́ bí òṣèré, ó ti kópa nínú sinimá àgbéléwò lédè Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì tí ó ju ọgọ́rùn-ún lọ.[1] [2]
Ìgbà èwe rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ní ìgbà èwe rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ kíkà ni Army Children School, Ìlọrin. Ó tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Sóbí Government School. Ó kàwé gboyè dìgírì àkọ́kọ́ ní ifáfitì ìjọba àpapọ̀ to wà ní ìpínlẹ̀ Èkó, (University of Lagos). Lọlá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà pẹ̀lú ère àṣàfihàn lórí tẹlifíṣọ̀nnù tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ "Ripples". Lẹ́yìn èyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni sinimá àgbéléwò ló ti kópa. Òun fún ara rẹ̀ tí ṣẹ olóòtú sinimá tó ju ọgbọ̀n lọ.[3] [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Lola Alao Biography - MyBioHub". MyBioHub. 2016-07-06. Retrieved 2019-11-24.
- ↑ Published (2015-12-15). "It’s nobody’s headache if I change my religion –Lola Alao". Punch Newspapers. Retrieved 2019-11-24.
- ↑ "Lola Alao Biography - Wikipedia - Profile". 360dopes. 2018-08-10. Retrieved 2019-11-24.
- ↑ ""I was born into a Muslim home" actress clears air on conversion". Pulse Nigeria. 2016-07-22. Retrieved 2019-11-24.