Lọlá Ògúnnáìkè

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lola Ogunnaike
Ọjọ́ìbíOṣù Kẹ̀sán 13, 1975 (1975-09-13) (ọmọ ọdún 48)
New York City
Orílẹ̀-èdèAmerican
Iléẹ̀kọ́ gígaNew York University
University of Virginia
Iṣẹ́Journalist
EmployerArise News
Olólùfẹ́Deen Solebo
Àwọn ọmọ1

Lọlá Ògúnnáìkè  jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó tún jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà (American) tí ó jẹ́ amúlùúdùn àti oníròyìn ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

Ìbẹ̀rẹ̀ ayé àti ẹ̀kọ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n bí Lọlá ní ojo ketala osu kesan odun 1975 (September 13, 1975) ní ilú New York City àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ méjèjì jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ J.E.B. Stuart High School ní Fairfax, ìlú Virginia. Ó gba oyè ẹ̀kọ́-kejì nínú iṣẹ́  ìròyìn ní ilé-ẹ̀kọ́ àgbà ti New York University , nígbà tí ó ti kọ́kọ́ gba oyè ìmọ̀ àkọ́kọ́  nínú ìmọ̀ Lítíréṣọ̀ Gẹ̀ẹ́sì (English literature) nílé ẹ̀kọ́ àgbà University of Virginia.

Ìgbòkè-gbodò iṣẹ́ rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ògúnnáìkè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oníròyìn ní ọdún1999 nípa ṣíṣe ìròyìn amúlùúdùn àti àwọn àṣà míràn tó bá jẹ yọ. Bákan náà ni ó ń jábọ̀ ìròyìn fún ile iṣẹ́ ìròyìn ti New York Times tí ó sì jẹ́ ọ̀gá ní ẹ̀ka ìròyìn amúlùúdùn tí ó ń ṣe pẹ̀lú bí ó ṣe dajú kọ àwọn olórin ilè Amẹ́ríkà ọlọ́kan ò jọ̀kan  bíi: Jennifer Lopez, Ozwald Boateng, Oprah Winfrey, tí ó sì ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ kóríyá nípa "Àṣà àti Ìsinmi" lápá kan inú ìwé ìròyìn náà. Bákan náà ló tún jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn  "Vibe magazine", ní èyí tí ó fi ń dá sí àwọn ìròyìn olóṣooṣù nípa orin àti àwọn ìròyìn tó jẹ mọ́ tàwọn ọ̀kọrin gbogbo. Ó sì tún kọ ìròyìn fún ìwé ìròyìn bíi: Rolling Stone, New York, Glamour, Details (magazine), Nylon, "New York Observer" àti "V Magazine". Ó sì tún wà lára àwọn ikọ̀ tí ó fọ̀rọ̀ wá aya olórí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà tẹ́lè ̣rí lẹ́nu wò ìyẹn: Michelle Obama lórí àbẹ̀wò rẹ̀ sí orílẹ̀ èdè South Africa. Lọlá tún jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn fún "New York Daily News","NOW," "Rush,  lórí ìròyin pàjáwìrì tí ó jẹ mọ́ ti amúlùud́ùn àti "Molloy" bákan náà ni ó tún jẹ́ ajábọ̀ ìròyìn fún ilé iṣẹ́ agbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti CNN’s “American Morning"[1] níbi tí ó ti ṣiṣẹ́ láti ọdún 2007 tí tí di 2009.[2][3]

Lọlá ti hàn lórí àwọn ètò ọlọ́kan ò jọ̀kan orí ẹrọ amóhùn-máwòrán bíi: NBC’s today Show, MTV àti VH1. Wọ́n kàá ní oṣù karùn ún ọdún 2007 (May 2007) mọ́ àwọn obìnrin aláwọ̀ dúdú tí ó nípa jùlọ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà (Ebony’s ‘150 Most Influential Blacks in America”). Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, òun ni ó dá Arise Entertainment 360 sile

ìgbésí ayé rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òun ni ìyàwó fún Deen Ṣólebọ, tí wọ́n sì bí ọmọ ọkùnrin kan ṣoṣo.[4][5]

Àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìjápọ̀ ìta[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

"Lola Ogunnaike's Official website". Archived from the original on 2018-08-19. Retrieved 2018-05-14.