Jump to content

Lagos television

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́


Lagos Television (tí à ń pè ní LTV), tàbí Lagos Weekend Television (tí à ń pè ní LWT, UHF channel 35, tí a tún máa ń pè ní LTV 8)[1] jẹ́ ilé-iṣẹ́ tẹlifísàn ti ìjọba Èkó ní Ìkẹjà, Ìpínlẹ̀ Èkó, ní Ilẹ̀ Nàìjíríà. Wọ́n dá tẹlifísàn ìpínlẹ̀ Èkó sílẹ̀ ní oṣù kẹwàá, ọdún 1980 lábẹ́ ìṣàkóso Alhaji Lateef Jankande láti pín ìsọfúnni fún àwọn aráàlú. níbití ó ti di ibùdó tẹlifísàn àkọ́kọ́ tí ìjọba ìpínlẹ̀ kan dá.[2] Ó bẹ̀rẹ̀ ìkéde ní Oṣù kọkànlá ọjọ́ kẹsan-án ti ọdún yẹn àti pé ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ Tẹlifísàn àkọ́kọ́ ní Ilẹ̀ Nàìjíríà láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn ìgbohùnsáfẹ́fẹ́ méjì (àwọn ẹgbẹ́ VHF àti UHF). Ní báyìí lórí ìkànnì UHF 35, ó jẹ́ ilé-iṣẹ́ Tẹlifísàn ti ìpínlẹ̀ àkọ́kọ́ tí ó wà lórí okùn sátẹ́láìtì DSTV ìkànnì 256 àti ní ìgbà díẹ̀ lórí ìkànnì Startimes 104.[3]

Ìdí tí wọ́n fi dá ilé-isẹ́ tẹlifísàn Èkó kalẹ̀ ni láti gba ìjọba ìpínlè Èkó láàyè láti pín àlàyé káàkiri fún gbogbo ènìyàn.[4]

Ní oṣù kẹ́sàn-án ọdún 1985, iná àràmàdà kan bá ibùdó ilé-iṣẹ́ Tẹlifísàn náà jẹ́, ilé-isẹ́ rẹ̀, ilé ìkàwé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé òṣìṣẹ́ náà. [5]

Àwọn Ìtọ́ka Sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. "Fashola orders environmental Sanitation at LTV 8". Encomium. Archived from the original on 11 November 2014. Retrieved 17 September 2014. 
  2. "About". Lagos Television. Lagos News. Politics. Entertainment. Events. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-02-17. Retrieved 2022-03-17. 
  3. "About". Lagos Television. Lagos News. Politics. Entertainment. Events. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-02-17. Retrieved 2022-04-23. 
  4. "About". Lagos Television. Lagos News. Politics. Entertainment. Events. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-02-17. Retrieved 2022-04-23. 
  5. "About". Lagos Television. Lagos News. Politics. Entertainment. Events. (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-02-17. Retrieved 2022-04-23.